Ẹgbẹ oṣelu Labour l'Ogun lawọn yoo ṣiṣẹ fun PDP nitori Aderinokun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 20, 2023

Ẹgbẹ oṣelu Labour l'Ogun lawọn yoo ṣiṣẹ fun PDP nitori Aderinokun


Ẹgbẹ oṣelu Labour nijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun ti sọ pe awọn ko ni oludije s'ipo aṣofin agba lẹkun aarin gbungbun ipinlẹ naa, to kọja Olumide Aderinokun, ẹni to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party, PDP.
 
Wọn lawọn ti ṣe agbeyẹwo gbogbo awọn oludije s'ipo naa kaakiri, ṣugbọn ti awọn ko ri ẹni to kaju ẹ, bi ko ṣe Olumide Aderinokun, nitori pe ifẹ araalu jẹ ẹ logun.
 
Ẹgbẹ naa ti igbakeji alaga wọn, Kayọde Fayọyin lewaju wọn ni wọn sọrọ naa nibi abẹwo ti Aderinokunṣe lọ si ijọba ibilẹ naa laipẹ yii.

Wọn ni awọn nifẹẹ si awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke ti Aderinokun n ṣe kaakiri ipinlẹ Ogun, paapaa ẹkun aarin gbungbun, ati pe ko si orọ ẹlẹyamẹya ninu ohun to n ṣe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI