Ijọba Kwara gbe owo iranwọ dide f'awọn ile-ẹkọ giga mẹrin to n lọ soko iparun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 19, 2023

Ijọba Kwara gbe owo iranwọ dide f'awọn ile-ẹkọ giga mẹrin to n lọ soko iparun


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe owo nla dide fun ile ẹkọ giga mẹrin ọtọọtọ, eyi ti ko ni jẹ ki wọn lọ soko iparun lojiji

Ọgọfa miliọnu naira ni ijọba ipinlẹ naa gbe kalẹ fun ile ẹkọ kọlẹẹji ati ti ẹkọ keu, to jẹ ti ijọba, eyi ti a gbọ pe wọn ni iṣoro ati ipenija owo
 
Kọmiṣanna fọrọ eto ẹkọ giga, Ọmọwe Alabi Afees Abọlọrẹ lo sọ eyi di mimọ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji, ọdun yii lakoko to n b'awọn akọroyin sọrọ niluu Ilọrin.

Ọmọwe Abọlọrẹ sọ pe owo naa lawọn ile ẹkọ ọhun yoo fi ṣe gbogbo awọn ohun to ti fẹẹ wọlẹ ninu ọgba ile ẹkọ wọn, eyi ti yoo si jẹ ki eto ẹkọ wọn pada si bo ṣe yẹ ko wa.
 
Nibẹ lo ti gba gbogbo awọn ọga agba lawọn ile ẹkọ naa lati ṣamulo awọn owo naa daadaa, ko ma ba a tun jẹ pe wọn yoo tun pada sinu awọn iṣoro to n doju kọ wọn.
 
Bẹẹ lo sọ pe iru awọn nnkan bayii ni Gomina AbdulRazaq ti n ṣe fun wọn latigba to ti gba iṣakoso lọdun 2019.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI