Ijọba Kwara pin ẹrọ amunawa mọkanla fawọn araalu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 1, 2023

Ijọba Kwara pin ẹrọ amunawa mọkanla fawọn araalu


Ijọba ipinlẹ Kwara ti pin ẹrọ amunawa ti a mọ si tiransifọma mọkanla si agbegbe mọkanla, lati lẹ jẹ k'awọn araalu jẹ igbadun ina ijọba to ja geere.

Kọmiṣanna feto ina, Ọnarebu AbdulWahab Fẹmi Agbaje Whyte lo sọrọ naa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee niluu Ilọrin.
 
Awọn agbegbe naa ni Ararọmi, ijọba ibilẹ Moro; Koko Ararọmi, ijọba ibilẹ Ifẹlodun; Pan African College niluu Ọffa; Offa Poly niluu Ọffa; Itẹsiwaju niluu Akerebiata, ijọba ibilẹ Ilọrin East; Babanloma, ijọba ibilẹ Ifẹlodun; ati agbegbe Niger/ Taiwo nijọba ibilẹ Ilọrin South.

Awọn yooku ni: Ambassador Estate to wa ni Zango, Ilọrin South; Abdulsalam Alao to wa ni Gaa- Akanbi, Ilọrin South; Edidi to wa nijọba ibilẹ Iṣin); ati Iṣọkanlagba Sapati Ile nijọba ibilẹ Asa

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI