Gbogbo awọn ọna alaye kaakiri ilu Iṣin, ijọba ibilẹ Iṣin ti sọ pe awọn ko ni oludije miran s'ipo gomina ipinlẹ Kwara, to kọja ẹni to ti n ṣakoso le wọn lori lati bi ọdun mẹrin din diẹ sẹyin, iyẹn Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.
Wọn lawọn ṣetan lati ṣagbatẹru ipolongo idibo fun AbdulRazaq lati pada s'ipo naa lẹẹkeji, nitori pe gbogbo ohun to n ṣe lo n tẹ wọn lọrun.
Bakan naa ni wọn sọ pe iṣakoso Gomina wọn kii ṣe pẹlu ojusaaju, bẹẹ si ni ko ni nnkan ṣe pẹlu ọrọ ẹlẹyamẹya, bi ko ṣe pe lori otitọ ati iwa ọmọluabi.
Gbogbo awọn ọba alaye naa lo sọrọ idaniloju yii nibi ayẹyẹ ayajọ ọdun kẹrinla ti Ọba Solomon Olugbemiga Oloyede, Atọbatẹlẹ keji gb'ọpa aṣẹ gẹgẹ bii Oluṣin tiluu Isanlu-Iṣin, ipinlẹ Kwara.
Ayẹyẹ naa to waye lọjọ Abamẹta, Satide ana ni wọn tun ti lo anfaani rẹ lati fi oye tuntun da Gomina AbdulRazaq lọla gẹgẹ bii Atunluṣe tiluuIsanlu-Iṣin, ti wọn si fi iyawo rẹ, Olufọlakẹ jẹ oye Yeye Atunluṣe tiluu Isanlu-Iṣin.
Lara awọn to wa nibẹ ni alaga TIC fun ijọba ibilẹ Iṣin, Ọnarebu Tunde Timothy Fadipẹ; Alaaji Mọshood Mustapha; Ọlọfa tiluu Ọffa, Ọba Mufutau Gbadamọsi Eṣuwoye keji, ati Olupo tiluu Ajaṣẹ-Ipo, Ọba Ismail Yahya Alebioṣu, to fi mọ Alaaji Kamọrudeen Yusuf.
Nigba to n gba ẹnu gbogbo ọmọ ilu naa sọrọ, Ọba Atóbatẹlẹ keji sọ pe idagbasoke ti Gomina AbdulRazaq ti mu ba ilu naa, paapaa ipinlẹ Kwara laaarin asiko to fi wa n'ijọba ti gbe ipinlẹ naa soke, eyi to ya awọn eeyan lẹnu, nitori pe wọn ko lero wi pe wọn le de ipo ti wọn wa lonii.
Kabiyesi ni awọn akanṣe iṣẹ idagbasoke to ti waye niluu Iṣin ko lẹgbẹ, nitori pe ilu naa ti dagbasoke kọja afẹnuroyin, to si tun ti n jẹ ki ilu naa maa lewaju.
O wa sọ pe awọn ko tun ni ẹlomiran t'awọn le fọwọ rẹ sọya wi pe yoo ṣe daadaa, to kọja ẹnikan ṣoṣo to nifẹẹ awọn eeyan rẹ denu, iyẹn Gomina AbdulRazaq.
No comments:
Post a Comment