Naijiria ti dara ju bi Buhari ṣe ba a lọdun 2015 - Lai Mohammed - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 20, 2023

Naijiria ti dara ju bi Buhari ṣe ba a lọdun 2015 - Lai Mohammed


Minisita fọrọ iroyin ati aṣa lorileede Naijiria, Alaaji Lai Mohammed ti sọ pe orileede Naijiria ti dara lasiko yii ju bi iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ba a lọdun 2015.

Lai Mohammed lo sọrọ naa lonii, ọjọ Aje, Mọnde, lakoko to n dahun ibeere lori amohunmaworan tijọba apapọ, Nigeria Television Authority (NTA).
 
O ni Buhari ti ṣe gbogbo ohun ti awọn ọmọ Naijiria n fẹ patapata, ati pe awọn ti wọn n fẹ lati ba Naijiria jẹ ni wọn n bu ẹnu atẹ lu iṣakoso Aarẹ Buhari, to si ni wọn ko to nnkan.
 
Lai Mohammed tẹsiwaju pe lara awọn aṣeyọri Buhari ni gbigba ijọba ibilẹ mẹtadinlọgbọn ti awọn Boko Haram ti gba tẹlẹ ṣaaju ọdun 2015.
 
Bakan naa lo sọ pe niṣe  ni Naijria maa n ra irẹsi lati orileede Thailand tẹlẹ, ṣugbọn ni bayii, nipa eto iṣẹ agbẹ, Naijiria ti n ṣe ounjé funra wọn bayii.
 
Siwaju sii lo ni labẹ iṣakoso aarẹ Buhari ni eeyan ti ko din ni miliọnu mẹwaa ti n gba ounjẹ ọfẹ lojumọ, ti miliọnu meji araalu si n gba owo ni gbogbo igba fun ilọsiwaju ara wọn.
 
"A ti pari opopona marosẹ Eko si Ibadan, pẹlu afara Niger keji, eyi ti wọn ti n ṣe lati bii ọgbọn ọdun sẹyin. Fun bii ọgbọn ọdun sẹyin, awọn ọmọ Naijiria ko mọ ohun to n jẹ ri rin irin ajo pẹlu ọkọ reluwee, ṣugbọn nigba ti Buhari de ipo agbara, o wa si imuṣẹ."

1 comment:

  1. Mr layi Mohammed, you and your family we safer at the end of your life for all what you are saying

    ReplyDelete

PÍN-IN KÁÀKIRI