Nitori ọwọngogo epo ati wahala owo naira, Gomina AbdulRazaq gbe aadọtalenigba miliọnu naira f'awọn oniṣẹ ọwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, February 23, 2023

Nitori ọwọngogo epo ati wahala owo naira, Gomina AbdulRazaq gbe aadọtalenigba miliọnu naira f'awọn oniṣẹ ọwọ


Lojuna lati jẹ ki ohun gbogbo rọrun f'awọn araalu lori ọwọngogo epo rọbii ati owo naira ti ko si nita, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti bu ọwọ lu owo to le ni aadọtalenigba (N267m) miliọnu naira f'awọn oniṣẹ ọwọ kaakiri ipinlẹ Kwara.
 
Gomina AbdulRazaq la gbọ pe o gbe iwe sọwedowo naa fun gbogbo awọn ẹgbẹ oniṣẹ ọwọ ati oniṣowo loriṣiriṣi niluu Ilọrin lonii, Ọjọbọ, Tọsidee.
 
O ni yoo jẹ ki gbogbo ohun to le koko dẹrọ, ati lati mu ki ọpọ awọn iṣẹ to ti n lọ soko iparun dide pada, ki eto ọrọ aje ipinlẹ naa le tubọ maa dagba soke sii.

Lara awọn to jẹ anfaani yii ni ẹgbẹ awọn Master Bakers and Caterers of Nigeria (AMBCN) ti wọn gba ọgọrun-un miliọnu naira; Tricycle Owners Association of Nigeria (TOAN) ti wọn gba ọgbọn miliọnu naira; Okada Riders Association of Nigeria (ORAN) ti wọn gba ọgbọno miliọnu naira; Road Transport Employers Association of Nigeria (RTEAN) ti wọn gba aadọta miliọnu naira; National Union of Road Transport Workers (NURTW) ti wọn gba aadọta miliọnu naira; ati Nigeria Union of Tailors, nipinlẹ Kwara, ti awọn gba miliọnu meje naira.
 
Nibẹ ni Gomina AbdulRazaq ti gba gbogbo awọn to jẹ anfaani yii lamọran lati ṣamulo awọn owo naa daadaa, ki igbe aye ati eto ọrọ aje wọn le tẹsiwaju, eyi ti yoo jẹ ki wọn de ilẹ ileri ti wọn ti n foju sọna fun.
 
Gbogbo awọn alaga awọn ẹgbẹ wọnyi ni wọn gbe oṣuba kare fun gomina wọn, lori iwa ọmọluabi ati ọkan ifẹ to fi n gba wọn ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI