O pari! Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP fẹgbẹ silẹ lojiji, o loun ti ba APC lọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 21, 2023

O pari! Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP fẹgbẹ silẹ lojiji, o loun ti ba APC lọ ni Kwara


Ọkan pataki lara awọn ọmọ ẹyin aarẹ ile igbimọ aṣofin agba lorileede yii tẹlẹ, Bukọla Saraki ni iroyin ti fi to wa leti pe o ti lọ darapọ mọ ẹgbẹ All Progressives Congress, APC n'ipinlẹ Kwara.
 
A gbọ pe ẹni naa kii ṣe ọmọ ẹyin lasan fun Saraki, wọn loun ni alaga ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP lẹkun ijọba ibilẹ Ariwa Kwara (Kwara North Senatorial).

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe akọkọ ree ti awọn ọmọ ẹyin Saraki lati inu ẹgbẹ oṣelu PDP yoo maa darapọ mọ APC lati ṣatilẹyin fun Gomina AbdulRazaq, ko le pada s'ipo naa lẹẹkeji, ṣugbọn eyi to tun ṣẹlẹ yii lo n kọ ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ lominu.
 
Malaamu Bala Waziri to jẹ alaga ẹgbẹ naa ni wọọdu kẹta ti Kaiama, nibi ti oludije s'ile igbimọ aṣofin agba lẹkun Ariwa Kwara ti jade lati ṣoju wọn l'Abuja.
 
Yatọ si pe Malaamu Waziri ba ẹgbẹ APC lọ, wọn lo tun ko gbogbo awọn ọmọ ẹyin rẹ lẹgbẹ PDP wọ APC, pẹlu ileri wi pe awọn yoo dibo rẹpẹtẹ fun AbdulRazaq.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI