Ọwọ Amọtẹkun tẹ Celestine to ko obitibiti ayederu owo tuntun lọ s'Ekiti lati na - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, February 22, 2023

Ọwọ Amọtẹkun tẹ Celestine to ko obitibiti ayederu owo tuntun lọ s'Ekiti lati na


B'awọn eeyan ko ba ṣọra wọn daadaa, ti wọn ko si kiyesara, afaimọ ni ko ma jẹ pe ayederu owo naira tuntun ni wọn yoo maa na kaakiri ipinlẹ Ekiti ati agbegbe ẹ, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe baale ile kan tọwọ Amọtẹkun tẹ laipẹ yii ti na pupọ ayederu owo naa f'awọn eeyan, ti wọn  ko si fura.

Ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira ti gbogbo rẹ jẹ ayederu ni wọn sọ pe ọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Celestine n na f'awọn eeyan n'ipinlẹ naa.
 
Gẹgẹ bi ọga agba pata fun ẹṣọ aabo Amọtẹkun nipinlẹ Ekiti, Ọgagunfẹyinti Joe Kọmọlafẹ ṣe sọ f'awọn akọroyin laipẹ yii, o ni ẹgbẹrun naira ni gbogbo ayederu owo ti Celestine lọ tẹ, ti iye rẹ si jẹ ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira.
 

Lakoko to n foju Celestine han niluu Ado-Ekiti lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ana, o sọ pe ilu Omuo-Ekiti, ijọba ibilẹ Ekiti East lọwọ ti tẹ Celestine.
 
O ni ẹnikan to n fi owo paarọ, iyẹn POS lo pariwo sita nigba to kofiri pe ayederu owo ni gbogbo owo ti ọkunrin naa ko wa foun, ko to di pe wọn ranṣẹ pe wọn.
 
Kọmọlafẹ ni bawọn ṣe debẹ ni Celestine ti bẹrẹ sii jẹwọ f'awọn pe ẹgbẹrun lọna igba ati aadọta naira, eyi ti gbogbo rẹ jẹ ẹgbẹrun kan naira ni owo toun ko kuro niluu Eko lati wa na niluu Omuo-Ekiti, lai mọ pe aṣiri maa pada tu.
 
Siwaju sii lo ni owo toun ti na ninu owo naa jẹ ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira ko to di pe aṣiri pada tu.
 
Ọga Amọtẹkun naa sọ pe awọno yoo lọ fa Celestine le awọn ọlọpaa lọwọ lati tubọ ṣe iwadii rẹ siwaju sii, ko to di pe wọn fi iya to to jẹ ẹ labẹ ofin.
 

Nibẹ lo ti wa rawọ ẹbẹ s'awọn araalu lati maa yẹ owo ti wọn n gba lọwọ eeyan ti wọn ko mọ ri wo daadaa, ko ma ba a jẹ pe ayederu ni. O lẹni to ba farabalẹ ni yoo mọ boya ayederu owo tabi ojulowo owo ni wọn na foun.
 
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe Orogbo ati Obi ni Celestine fẹran lati maa fi owo onaa ra lọwọ awọn eeyan kaakiri.
 
Celestine nigba to n b'awọn akọroyin sọrọ jẹ o di mimọ pe ilu Isanlu to wa nipinlẹ Kogi loun n ko owo yooku lọ lati fi lọ ra Obi ati Orogbo, ko to di pe aṣiri tu sita.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI