Ọwọ tẹ Mutiu, Abdulsalam ati Fatai pẹlu ori oku l'Oṣogbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, February 12, 2023

Ọwọ tẹ Mutiu, Abdulsalam ati Fatai pẹlu ori oku l'Oṣogbo


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti rọwọ to awọn ọrẹ mẹta kan ti wọn ba ori oku lọwọ wọn niluu Oṣogbo, ti wọn si lo ti di kankan ki wọn foju winna ofin laipẹ.
 
Awọn mẹta naa ni Alfa Mutiu Ọlanrewaju, ẹni ọdun mẹrinlelogun; Adebọwale Abdulsalam, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn ati Fatai Akanji, ẹni ọdun mẹtadinlogoji.
 
Gẹgẹ bi alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Yẹmisi Ọpalọla ṣe ṣalaye lakoko to n foju awọn ọdaran naa han f'awọn akọroyin niluu Oṣogbo laipẹ yii, o ni ọsan ganri lọwọ palaba wọn segi.
 
Ninu ọrọ rẹ, o ni nnkan bi aago kan aabọ ọsan lawọn ọlọpaa da mọto ayọkẹlẹ alawọ pupa kan duro lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kinni, ọdun yii, lagbegbe Ifọn to wa loju ọna Ogbomọṣọ.

Awọn marun-un lo sọ pe wọn wa ninu mọto Golf ti ko ni nọmba idanimọ naa. O ni bi awọn ọlọpaa ṣe da wọn duro, ni wọn ti sọ f'awọn to wa ninu ẹ pe ki wọn bọ silẹ, ti wọn si ri apo gaari ti wọn gbe ṣeyin mọto ọhun.

Nibi t'awọn ọlọpaa ti n yẹ gaari naa wo, ni wọn ti ṣalabapade ọra dudu meje kan to kun fun ẹya ara eeyan tutu, to si jẹ iyalẹnu fun pupọ awọn to wa nibẹ.

Mutiu ni wọn lo ni ẹru buruku ọhun, to si jẹwọ pe ilu Ogbomọṣọ loun ti ri ra a lọwọ Alfa Adebọwale. Mutiu lọmọ bibi ilu Ifọn-Ọṣun to wa lagbegbe Janta loun.
 
Nibẹ lo ti sọ pe kii ṣe akọkọ ree toun yoo maa ra ori ati ẹya ara oku, to si ni bii ẹgbẹrun meji si marun-un naira loun naa n ra wọn, bo ba si ṣe to ni.
 
Eyi lo mu kawọn ọlọpaa lọ gbe Alfa lagbegbe Ilogbo to wa niluu Ogbomọṣọ, to si tun jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ba agba nla to kun fun ẹya ara oku
 
Alfa naa lo pada jẹwọ pe ẹnikan wa toun naa maa n ra ẹya ara oku naa lọwọ ẹ, ati pe Alayọ lorukọ ẹ, ilu Ogbomọṣọ loun naa si n gbe. O ni oṣiṣẹ aabo itẹku ni Alayọ, bo tilẹ jẹ pe oun ti na papa bora. 
 
O wa jẹ ko ye wa pe gbogbo wọn lọwọ palaba wọn ti segi, ti wọn si ti foju ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI