Wọn ju baba agbalagba sẹwọn ọdun marun-un, ọmọ ọdun mẹjọ lo fipa ja ibale rẹ l'Ẹdo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, February 13, 2023

Wọn ju baba agbalagba sẹwọn ọdun marun-un, ọmọ ọdun mẹjọ lo fipa ja ibale rẹ l'Ẹdo


Ile ẹjọ Majisireeti to wa nipinlẹ Edo ti ju baba agbalagba kan,
Frederick Agbozuadu, sẹwọn ọdun marun-un lori ẹsun fifipa ba ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹjọ laṣepọ, to si tun ja ibale rẹ.

Ijọba ibilẹ kan ti wọn pe ni Akoko-Edo, ipinlẹ Edo la gbọ pe Frederick ti ba ọmọ naa laṣepọ.

Ninu atẹjade ti ajọ alaanu kan, Brave Heart Initiative to gbe baba naa lọ sile ẹjọ gbe jade lọjọ Aiku, Sannde to kọja, wọn ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹsan, oṣu keji, ọdun 2023 ni ile ẹjọ naa gbe idajọ kalẹ.
  
Ajọ naa lo jẹ ka mọ pe ile ẹjọ ko faaye silẹ fun owo itanran, bi ko ṣe pe ko lọ fi ẹwọn ọdun marun-un naa gbara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI