Wọn ju Destiny to n fi orukọ Ninalowo, gbajumọ oṣere tiata lu awọn eeyan ni jibiti sẹwọn ọdun meji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, February 21, 2023

Wọn ju Destiny to n fi orukọ Ninalowo, gbajumọ oṣere tiata lu awọn eeyan ni jibiti sẹwọn ọdun meji


Ile ẹọ giga apapọ to wa niluu Warri, ipinlẹ Delta ti ju gendekunrin kan,
Omoghan Destiny Igbinosa ṣewọn ọdun meji pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun wi pe o n fi orukọ olorukọ lu awọn eeyan ni jibiti.
 
Onidajọ Okon Abang lo ju Destiny sẹwọn naa, ẹni to sọ pe ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo lọ, eyi to si ti gba owo rẹpẹtẹ lọwọ awọn alaimọkan nipa ẹtanjẹ.
 
Yatọ si Destiny ti wọn ju sẹwọn naa, wọn tun ju Onukwugha Favour ati Lawrence David naa sẹwọn lori ẹsun jibiti ori ayelujara kan naa.
 
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, la gbọ pe wọn wọ awọn mẹtẹẹta yii lọ sile ẹjọ.
 
EFCC sọ pe aarin ọdun 2021 si 2022 ni Destiny n fi orukọ gbajugbaja oṣere tiata nni, Ninalowo Bọlanle  fi lu jibiti naa, ko to di pe akara rẹ tu s'epo.
 
Orukọ naa ni wọn lo fi f'awọn iwe kan ranṣẹ si ẹnikan ti wọn pe ni Newon Quanon lori ayelujara lati le wọle sii lara, ko si gba owo lọwọ ẹ.
 
Bakan naa ni Favour, wọn loun n lo orukọ Mariah_1812 lati maa fi lu jibiti kaakiri.
 
Awọn mẹtẹẹ yii ni wọn pada sọ pe lotitọ lawọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.
 
Onidajọ Abang nigba to n gbe idajọ kalẹ paṣẹ pe ki Destiny lọ fi ẹwọn ọdun meji gbara, tabi ko san miliọnu kan naira gẹgẹ bi owo itanran, bẹẹ ni yoo si tun gbagbe $2,235 ati foonu ẹ sọwọ ijọba.
 
Bakan naa ni ti Favour ati David, ile ẹjọ ju awọn mejeeji sẹwọn ọdun kọọkan, tabi ki wọn san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun lọna igba naira gẹgẹ bi owo itanran, ati pe wọn yoo gbagbe foonu wọn sọwọ ijọba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI