Ẹ gba mi o, Koko-Zaria fẹẹ pa mi danu o - Adunni Ade pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, March 2, 2023

Ẹ gba mi o, Koko-Zaria fẹẹ pa mi danu o - Adunni Ade pariwo sita


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Adunni Ade ti fẹsun kan ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ pataki fun ọga awọn onimọto l'Ekoo, MC Oluomo, iyẹn Koko Zaria, wi pe o n lepa ẹmi oun, ati pe ki awọn eeyan gba oun lọwọ.
 
Adunni Ade tun sọ pe bi nnkan ba ṣẹlẹ si oun, Koko Zaria ni ki wọn mu, nitori pe oriṣiriṣi idunkooko iku loun ti n ri gba lati ọdọ rẹ.

Ninu fọnran ti Adunnu Ade gbe sori ikanni Insitagiraamu rẹ laipẹ yii, o sọ pe ẹmi oun ko de mọ lọwọ ọkunrin naa, nitori bo ṣe n sọ pe awọn ko gbọdọ foju kan ara mọ ti aye maa fi parẹ.

Wahala yii la gbọ pe o bẹrẹ nigba ti Adunni bu ẹnu atẹ lu awọn ilu mọ-ọn ka wi pe wọn gba owo lọwọ oloṣelu kan to tun jẹ oludije sipo aarẹ lati polongo ibo fun un, eyi to mu k'awọn ti ọrọ naa kan lati jade sọrọ abuku sii wi pe ko si nnkan to kan an.
 
Kokozaria toun naa n polongo ibo fun oloṣelu ọhun lo jade sita lati maa pariwo wi pe oun ko gbọdọ ri Adunni ati Kẹmi Afọlabi nigboro aye lori bi wọn ṣe n sọrọ abuku s'awọn to gba owo lọwọ oloṣelu fun ipolongo ibo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI