Nnkan de! Awọn ajagungbalẹ dana sun ile Baalẹ ilu, wọn tun n f'iku wa a kaakiri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, March 5, 2023

Nnkan de! Awọn ajagungbalẹ dana sun ile Baalẹ ilu, wọn tun n f'iku wa a kaakiri


Kani kii ṣe ori to ko Baalẹ ilu Ẹrẹbẹ to wa niluu Omu-Ijẹbu, ijọba ibilẹ Odogbolu, ipinlẹ Ogun, Oloye Oluṣẹgun Lawal yọ lọwọ iku ojiji, boya ko ba ti dẹni igbagbe lasiko ta a pari akojọpọ iroyin yii.

Inu oṣu kẹjọ, ọdun to kọja la gbọ pe awọn ajagungbalẹ ya wọ ilu naa, pẹlu erongba lati maa ta ilẹ lọna aitọ, ti wọn si ni Oloye Oluṣẹgun Lawal ko gba fun wọn, eyi ti wọn lo bi wọn ninu.
 
Wọn ni bi iwa Baalẹ yii ko ṣe tẹ awọn ajagungbalẹ naa lọrun, lo mu ki wọn maa lepa ẹmi rẹ kaakiri, ti wọn si wa a dele rẹ ninu oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja pẹlu erongba lati pa a, ṣugbọn ti wọn ko ba a.
 
Igba ti wọn ko ba a nile lo mu ki wọn dana sun ile rẹ, to si jona di eeru. Awọn ara agbegbe naa ni wọn sare pe Baalẹ yii, ẹni ti wọn lo wa niluu Ijẹbu-Ode lati fi to o leti, toun naa ko si duro, ti wọn ni loju ẹsẹ lo wa a wo ohun to ṣẹlẹ.
 
Latibẹ la gbọ pe o ti kọwe ẹsun si gomina ipinlẹ Ogun, Kọmiṣanna ọlọpaa ati gbogbo awọn ti ọrọ kan patapata, lati fi to wọn leti, ki wọn si le gbe igbesẹ.
 
Ninu iwadii lọwọ ti tẹ mẹta ninu awọn to lewaju lọ dana sun ile Baalẹ ọhun, t'awọn yooku si na papa bora, koda ti wọn ko tii ri wọn mu dasiko yii.
 
Awọn mẹta tọwọ tẹ naa ni Adeyẹmi Oluwọle, Adebọla Ogunkọya, ati Joseph Fidelis. A gbọ pe awọn ọlọpaa ti foju wọn ba ile ẹjọ Majisireeti to wa niluu Odogbolu.

Onidajọ A. Ogunmodede, nigba to n sọrọ l'Ọjọru, Wẹsidee, ọsẹ yii paṣẹ pe ki wọn ṣi lọ fi wọn pamọ sọgba ẹwọn titi digba ti igbẹjọ miran yoo fi waye lọjọ kejidinlogun, oṣu kẹrin, ọdun 2023 ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI