Ogbologbo adigunjale mẹta ha sọwọ ọlọpaa l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 15, 2023

Ogbologbo adigunjale mẹta ha sọwọ ọlọpaa l'Ogun


'Ẹ ṣe wa jẹjẹ, ẹ f'oju aanu wo wa, a ko mọ pe aṣiri maa pada tu', lọrọ ẹbẹ to n jade lẹnu awọn ọrẹ mẹta kan ti a gbọ pe wọn ko niṣẹ meji ju iṣẹ adigunjale lọ, ti a si gbọ pe agbegbe Ewekoro ni wọn fẹran lati maa ṣọṣẹ wọn.
 
Ọjọ kẹtala, oṣu keta, ọdun 2023 ti a wa yii ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn mẹtẹẹta, lẹyin olobo t'awọn kan ta wọn.

Awọn afurasi ọdaran naa, Ahmẹd Isiaha, Sunday Ajibọla ati Jimọh Wahab ni iroyin fi to wa leti pe wọn lọ digun ja awọn ara agbegbe Apomu to wa nijọba ibilẹ Ewekoro,ko to di pe wọn ta awọn ọlọpaa lolobo.
 
Wọn loju ẹsẹ t'awọn ọlọpaa ti debẹ lawọn adigunjale naa ti wọn sọ pe mẹrin ni wọn ti juba ehoro, ti a si gbọ pe pẹlu iranlọwọ awọn ara agbegbe naa, mẹta lọwọ tẹ, ti ẹnikan yooku si salọ.
 
Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ wọn ni  ibọn ilewọ ẹlẹnu meji, ọta ibọn marun-un, ọkada Bajaj to ni nọmba idanimọ TTN 975 VU, ati Ọkada maruwa TVS to ni nọmba idanimọ JBD 353 W.

Ni bayii, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Frank Mba ti paṣẹ pe ki iwadii tubọ tẹsiwaju ko to di pe wọn lọ foju wọn ba ile ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI