Omije kikoro lọjọ ti wọn sinku agunbanirọ to ku ninu ijamba reluwee l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, March 15, 2023

Omije kikoro lọjọ ti wọn sinku agunbanirọ to ku ninu ijamba reluwee l'Ekoo


Beeyan ba wa nibi ti wọn ti sinku ọmọbinrin, Ọrẹoluwa Aina, ẹni ọdun mejidinlọgbọn to ku ninu ijamba ọkọ reluwee ati bọọsi akero ijọba ipinlẹ Ekoo ti wọn n pe ni BRT lọsẹ to kọja yii, koda bi onitọhun jẹ ori ahun, yoo bu sẹkun.
 
Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ to kọja yii ni ijamba naa waye lagbegbe PWD to wa ni Ikẹja
 
rẹoluwa Aina wa lara awọn mẹfa to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọhun.

Ẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ eto Ẹkọ, t'ijọba Eko ti wọn pe ni Curriculum Services Department to wa ni Alausa la gbọ pe Ọrẹoluwa ti n ṣe agunbanirọ rẹ.
 
Itẹkuu ti Atan ni wọn sinku rẹ si, nibi ti ẹsẹ ko ti gbero
No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI