Ọmọ ọdun mọkanla ati mẹtala ja ṣọọbu oni ṣọọbu l'Oṣogbo, wọn ji ounjẹ ati owo ko - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 28, 2023

Ọmọ ọdun mọkanla ati mẹtala ja ṣọọbu oni ṣọọbu l'Oṣogbo, wọn ji ounjẹ ati owo ko


Ọwọ ileeṣẹ eto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun ti tẹ awọn ọmọdekunrin meji kan tọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkanla si mẹtala lọ, lori ẹsun ole jija.
 
Ṣọọbu kan ti wọn ti n taja la gbọ pe awọn mejeeji ti lọ jale, ti wọn si ji ọpọ ounjẹ ati owo ko nibẹ, iyẹn niluu Oṣogbo, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.
 
Agbegbe Aṣubiaro niluu Oṣogbo ni ṣọọbu naa wa.

Olori ẹṣọ aabo Amọtẹkun n'ipinlẹ naa, Ajagunfẹyinti Bashir Adewinmbi, nigba to n f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ l'ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, onii, o sọ pe aarọ ọjọ Abamẹta, Satide ni awọn ọmọ naa lọ jale ọhun.
 
O ni awọn nnkan bii kaadi ipe, ounjẹ awọn ọmọde ti wọn n pe ni Noodles, ọti ẹlẹrindodo ati awọn owo ni wọn ji ko, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ wọn ni irọlẹ ọjọ naa, iyẹn ni nnkan bi aago mẹfa kọja iṣẹju mẹrinlelogun.

Adewinmbi gba awọn eeyan lamọran lati maa mojuto ohun ini wọn loore koore.
 
Bẹẹ lo sọ pe awọn ọmọ naa ti jẹwọ pe lotitọ lawọn jale ọhun, ati pe ninu awọn ẹru ti wọn ji ko ṣi wa lọwọ awọn.
 
O tun fi kun un pe awọn obi awọn ọmọ naa ti wa lati bẹbẹ, ati pe ẹni to ni ṣọọbu naa ti gba wi pe ki wọn f'awọn ọmọ naa silẹ, nitori t'awọn obi wọn ti gba lati san owo gbogbo nnkan ti wọn ji ko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI