Wọn fi Sabo City, gbajumọ sọrọsọrọ j'oye Baba Adinni l'Abẹokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, March 28, 2023

Wọn fi Sabo City, gbajumọ sọrọsọrọ j'oye Baba Adinni l'Abẹokuta


Ẹsẹ ko gbero niluu Abẹokuta lọjọ Aiku, Sannde to kọja yii nibi ti ijọ ẹlẹ Musulumi ti wọn pe ni Modrasat Daru-Salam ti fi gbajugbaja sọrọsọrọ ori redio nni, Alaaji Saburi Ọladeji, ẹni tọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Sabo-City j'oye nla ti ko wọpọ.
 
Oye Baba Adinni ni ijọ mmusulumi naa fi Sabo City jẹ, latari awọn ipa to n ko ninu eto idagbasoke ijọ naa, paapaa ẹsin musulumi jakejado.
 
Eto ọhun to waye ninu gbagede ọgba ile ẹkọ golden Grace to wa ladugbo Oluwo, agbegbe Onikolobo, Abẹokuta, ipinlẹ Ogun lo kun fun awọn agba musulumi kaakiri ipinlẹ naa.
 
Nigba to n sọrọ lori idi ti wọn fi yan Sabo City gẹgẹ bi Baba Adinni ijọ naa, Mukadam Abdul-Hameed Akorede Muh. Jimọh {Khalizini Amoye} sọ pe iwa ọkunrin naa lo fa a, ti wọn fi yan an.

Yatọ si pe wọn fi Sabo-City joye Baba Adinni, wọn tun lo anfaani rẹ lati fun awọn to ti ko ipa to jọju ninu ijọ naa ni awọọdu lati fi mọ riri ipa ti wọn n ko.

Odu ni Sabo City, kii ṣaimọ f'oloko lagboole pedepede, ti awọn eeyan si n gbadun ẹ daadaa, nipa awọn eto ọlọkan-o-jọkan to maa n ṣe ni gbogbo igba.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI