Aye o! Agbara ojo gbe ọmọ ọdun mẹwaa lọ, bẹẹ lafẹfẹ iji tun pa eeyan mẹfa danu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 21, 2023

Aye o! Agbara ojo gbe ọmọ ọdun mẹwaa lọ, bẹẹ lafẹfẹ iji tun pa eeyan mẹfa danu


Ijọba ipinlẹ Delta ti fidi rẹ mulẹ pe ko din ni eeyan meje ti agbara ojo pa danu, to si tun ba ọpọlọpọ dukia olowo iyebiye jẹ, eyi ti wọn lo kọja sisọ.
 
Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii ni ijọba Delta fidi rẹ mulẹ, bẹẹ ni wọn sọ pe ọpọ awọn eeyan lo tun farapa yannayanna.

Kọmiṣanna fọrọ eto iroyin, Ọgbẹni Charles Aniagwu, lo fidi rẹ mulẹ f'awọn akọroyin nibi ipade awọn oniroyin to ṣe niluu Asaba, to si jẹ ko di mimọ pe ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹwaa kan naa wa lara awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
 
Aniagwu, sọ pe  agbegbe Oko to wa ni Oshimili ati Okpanam, ijọba ibilẹ Oshimili South North niṣẹlẹ ọhun ti waye.

O ni bi ojo naa ṣe bẹrẹ, lo wo ile kan, to si tun wo awọn igi nla-nla danu, nibi ti wọn ti padanu eeyan mẹfa, to si lawọn to farapa ti wa l'ọsibitu Asaba ti wọn ti n gba itọju.
 
“Iji naa lo fa ojo lile l'Ọjọru, Wẹsidee to kọja yii lagbegbe Oko. Eeyan mẹfa la padanu nigba ti ojo naa wo ile kan ati awọn igi.

“Awọn yooku ti wọn farapa kọja sisọ ni wọn ti wa ni Asaba Specialist Hospital, nigba ti awọn marun-un yooku ti wọn fara kaaṣa naa kan rọra ṣeṣe lasan ni.”

Siwaju sii lo tun sọ pe “Iṣẹlẹ miran tun ṣẹlẹ to ba ni lọkan jẹ pupọ. Lagbegbe Okotomi to wa ni Okpanam, ijọba ipinlẹ yii n gbe igbesẹ lati daabo bo awọn eeyan lọwọ agbara ati omiyale.

“Ṣugbọn latari ojo ti rọ l'Ọjọru, Wẹsidee, ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹwaa kan to n bọ lati ile ijọsin nirọlẹ lo yọ ṣubu sinu koto kan ti wọn n ṣe lọwọ.

“Ati pe nitori omi to pọ ninu koto naa, omi yii gbe ọmọ naa lọ. Gbogbo akitiyan lati ri ọmọ naa lo ja si pabo, koda, a ṣi n ṣiṣẹ lori bi a ṣe maa rii titi di asiko yii

“Iṣẹlẹ to ba ni lọkan jẹ ni, mo si n gbadura pe ki Ọlọrun rẹ awọn obi ọmọ naa lẹkun.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI