Aye o! Awọn agbebọn pa pasitọ ijọ Oyedepo danu ni Kogi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, April 8, 2023

Aye o! Awọn agbebọn pa pasitọ ijọ Oyedepo danu ni Kogi


Awọn agbebọn kan ni iroyin fi to wa leti pe wọn ti yinbọn pa ọkan lara awọn pasitọ ijọ Living Faith to jẹ ti Baba David Oyedepo, Jacob Wodi Hulobu danu.
 
Jacob la gbọ pe o jẹ alakoso ijọ naa ti awọn eeyan tun n pe ni Winners Chapel, eyi to wa lagbegbe Aloko-Oganenigwu, ijọba ibilẹ Dekina, ipinlẹ Kogi.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn niṣe l'awọn agbebọn naa yawọ inu ṣọọṣi wọn, ti wọn si dabọn bọle, ṣugbọn ti gbogbo wọn na papa bora.
 
Igba ti wọn ni ariwo naa lọ silẹ diẹ ni nnkan bi ọwọ ọsan, ni Jacob pada lọ si ṣọọṣi lati wo ohun to n ṣẹlẹ nibẹ, boya awọn agbebọn naa ti lọ.
 
Loju ẹsẹ ni wọn sọ pe awọn agbebọn naa yinbọn fun un lati ọọkan, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, to b'awọn akọroyin sọrọ ṣalaye pe
“O salọ lakoko ti a n ṣe isin laaarọ. Niṣe lo ro pe gbogbo nnkan ti lọ silẹ ni, o si pada lọ si ṣọọṣi lati wo o boya wọn ko ṣe ijamba fun ijọ. Asiko naa ni wọn yinbọn fun un, to si ku.”
 
Ṣaaju asiko naa, a gbọ pe Jacob ṣi gbe ohun to ṣẹlẹ sori fesibuuku, lati dupẹ lọwọ Ọlọrun bi ori ṣe ko oun ati awọn ọmọ ijọ rẹ yọ lọwọ awọn agbebọn naa.

A tiẹ gbọ pe Jacob ti gbe isọji irọlẹ ọlọjọ mẹta to pe ni ‘Let the fire fall: Three nights of Wanders,’ kalẹ, eyi to fẹẹ waye lọjọ kẹtala si ọjọ kẹẹdogun, oṣu yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI