Gbogbo ẹyin ti mo ba ti ṣẹ, ẹ dariji mi - Gandujẹ bẹbẹ bi iṣakoso rẹ ṣe fẹẹ kogba wọle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 17, 2023

Gbogbo ẹyin ti mo ba ti ṣẹ, ẹ dariji mi - Gandujẹ bẹbẹ bi iṣakoso rẹ ṣe fẹẹ kogba wọle


Gomina Abdullahi Ganduje ti ipinlẹ Kano ti rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn to ba ti fi iṣejọba rẹ da laamu nipinlẹ naa, ati gbogbo awọn ti iṣakoso rẹ ko tẹ lọrun lati dariji oun.
 
O ni ori ko le ṣe ko ma min lọrun, fun idi eyi, kii ṣe ẹjọ oun lati gbena woju ẹnikẹni, bi ko ṣe lati wa idagbasoke ati ilọsiwaju ba ipinlẹ naa ni gbogbo ọna.
 
Ganduje ni iṣakoso rẹ yoo d'opin gẹgẹ bii gomina pinlẹ Kano lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun, ọdun ti a wa yii.
 
Nibi eto waasi Ramadaani ti mọṣalaṣi Al Furqan Juma’at to wa lagbegbe Nasarawa GRA, ilu Kano, ni Ganduje ti rawọ ẹbẹ naa, to si ni ki wọn gba alaafia laaye.
 
Gẹgẹ bo ṣe sọ “Mo ti dariji gbogbo ti wọn ti figba an gbena woju mi, tabi ti wọn sọrọ abuku si mi pẹlu ipo ti mo di mu. Lọdọ temi naa, mo n bẹbẹ pe ki ẹ dari gbogbo aṣiṣe mi ji mi, bi mo ba ti ṣẹ yin.”
 
O ni igbesẹ naa waye nitori ipo ti ẹsin Islam di mu, to si ni “gẹgẹ bi awọn adari wa ninu mọṣalaṣi yii ṣe sọ, idariji di ipo to ṣe pataki mu ninu ẹsin wa.”
 
“Iṣakoso mi gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Kano ti d'opin, eyi si ni ọrọ idagbere mi. Mo ki gbogbo yin daadaa si ohun to dara. Fun awọn ti a ti ṣẹ, ẹ dariji wa, ni ọdọ temi, mo ti dariji gbogbo awọn to ṣẹ mi ni oniruuru ọna, ko si nii ṣe pẹlu bi ẹṣẹ wọn ṣe to.”
 
Gomina ti awọn araalu ṣẹṣẹ dibo yan labẹ asia ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party, Abba Kabiru ni Ganduje yoo gbe ijọba silẹ fun lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023 ti a wa yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI