Bi iyawo yin ba n yan ale, to n sun kaakiri ile ọkunrin, ẹ forijii - Bukunmi gb'awọn baale ile lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, April 17, 2023

Bi iyawo yin ba n yan ale, to n sun kaakiri ile ọkunrin, ẹ forijii - Bukunmi gb'awọn baale ile lamọran


Gbajugbaja oṣerebinrin nni, Bukunmi Oluwaṣina ti gba gbogbo awọn baale ile lamọran lati maa fi oriji iyawo wọn to ba n sun ile ọkunrin kaakiri, to si ni gbigbagbe aṣiṣẹ lo le jẹ ki ifẹ ololufẹ pẹ.
 
Inu fọnran kan ti Bukunmi gbe soju opo Instagram rẹ lo ti ṣalaye pe ki baale ile maa foriji iyawo wọn ba n sun kaakiri ile ọkunrin lo dara ju.
 
Bakan naa lo sọ pe ki iru awọn ọkunrin bayii tun maa gbadura fun awọn iyawo wọn to ba n rin irinkurin.
 
Ninu fọnran naa lo tun ti jẹ ko di mimọ pe obinrin nikan lawọn eeyan kan maa n gba lamọran lasan, wọn kii sọrọ nipa eyi t'awọn ọkunrin n ṣe.

“Bi iyawo rẹ ba n sun kaakiri, dariji, ki o si gbadura fun un, o le maa le nnkan to pọ kọja, ohun ti Olọrun ko le ṣe, ko tii si.

“Ko ma lọ dabi ẹni pe ko sẹni to le gba ọkunrin lamọran”.

“Bi obinrin rẹ ba sun pẹlu ọrẹ timọtimọ rẹ, ko ṣee ṣe ki ẹ fi silẹ fun ọkunrin tuntun naa nitori pe o sun pẹlu ẹ, Rara! Waa ja fun obinrin rẹ, nitori pe obinrin rẹ ni.

“To ba jẹ pe o ti gbagbe wi pe ọrẹ timọtimọ rẹ ni nkọ, bi awọn obinrin ṣe ri niyẹn, a maa n tete gbagbe nnkan, ifẹ si ni iforiji.

“Abi ki iyawo rẹ tiẹ lọ ṣeṣi ba ẹlomiran laṣepọ nita, ko si wa loyun, ibukun ni gbogbo awọn ọmọ jẹ, ko sẹni to kọja aṣiṣe, ẹ ni lati gba ọmọ naa, ẹ dariji iyawo yin, ki ẹ si maa ba igbesi aye yin lọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI