Iṣọ oru ni ọkọ atiyawo n lọ ki wọn to ji wọn gbe l'Ọṣun, wọn ti gba wọn jade - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, April 21, 2023

Iṣọ oru ni ọkọ atiyawo n lọ ki wọn to ji wọn gbe l'Ọṣun, wọn ti gba wọn jade


Orin ọpẹ lo gba ẹnu mọlẹbi ọkọ atiyawo kan ti awọn ajinigbe jigbe laipẹ yii nipinlẹ Ọṣun, lori bawọn ọlọpaa ṣe ri wọn gba jade pada, ti wọn si ti pada sile wọn layọ ati alaafia.
 
Iṣọ oru la gbọ pe ọkọ ati iyawo naa, Ọgbẹni Andrew Jona ati iyawọ rẹ, Margaret Jonah, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ko to di pe wọn ji wọn gbe.
 
Ori ọkada la gbọ pe awọn mejeeji wa loju ọna Iragbiji si Kelebe lati lọ ṣe iṣọ oru niluu Oṣogbo. Ibẹ ni wọn lawọn ajinigbe to ti duro loju ọna ti da wọn duro, ti wọn si ji wọn gbe wọnu igbo lọ.
 
Loju ẹsẹ ti iroyin naa ti tẹ awọn ọlọpaa lọwọ la gbọ pe wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, ti wọn si pada ṣawari buba wọn ninu igbọ kijikiji, ko ti di pe wọn koju wọn.
 
Nigba tawọn mejeeji n sọrọ, wọn ni idunnu ati ayọ nla lo jẹ fun wọn pe wọn ko padanu ẹmi wọn sọwọ awọn ajinigbe naa.
 
“Wọn lawọn maa pa wa danu, awọn yoo si ta oku wa f'awọn to n ṣetutu owo bi awọn mọlẹbi wa ko ba wa lati ko owo ti wọn n beere silẹ f'awọn.
 
“B'awọn ọlọpaa ṣe n yinbọn lakọ-lakọ lo bori t'awọn ajinigbe naa. Eyi lo jẹ ki wọn fi emi ati ọkọ mi silẹ, ti wọn si salọ, nitori wọn ko fẹ ki ọwọ tẹ wọn.
 
“Bi a ṣe n gbọ iro ibọn, awọn ajinigbe naa fi wa silẹ, wọn si juba ehoro.  Igba to ya la bẹrẹ sii gbọ ti awọn kan n pariwo orukọ ọkọ mi, eyi lo jẹ ka mọ pe awọn ọlọpaa lo wa gba wa silẹ.
 
“A dupẹ lọwọ awọn ọlọpaa to n gbogun ti awọn ajinigbe nipinlẹ Ọṣun ti wọn wa gba silẹ.”
 
Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa nigba to n sọrọ sọ pe niṣe lawọn ajinigbe naa doju ibọn kọ awọn ọlọpaa lakoko naa, ṣugbọn to sọ pe ọkan lara wọn dagbere faye nibẹ, ti awọn yoou si na papa bora.
 
Ọpalọla sọ pe awọn ri ibọn kan gba lara awọn ibọn ti wọn fi n ṣiṣẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI