AbdulRazag b'awọn olori ile igbimọ aṣofin Kwara yọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 18, 2023

AbdulRazag b'awọn olori ile igbimọ aṣofin Kwara yọ


L'ọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tusidee, to kọja yii ni Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ba gbogbo awọn olori ati ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara yọ lori bi wọn ṣe bẹrẹ iṣakoso tuntun.
 
Gomina AbdulRazaq, ẹni to tun jẹ olori awọn gomina ilẹ Naijiria lapapọ lo ba gbogbo aṣofin naa yọ, bi wọn ṣe n bẹrẹ eto ile igbimọ aṣofin kẹwaa nipinlẹ naa, iyẹn nibi ibura ti wọn ṣe lọjọ kẹtala, oṣu kẹfa, ọdun 2023.
 
Nibẹ ni gomina ti gbe oṣuba kare f'awọn aṣofin naa lori bi wọn ṣe tukọ eto idibo to gbe awọn olori tuntun naa wọle, ati bi idibo ọhun ṣe lọ ni irọwọ irọsẹ.

O ni ipa rere ni wọn fi lelẹ, pẹlu bi wọn ṣe tun dibo yan Ọnarebu Yakubu Danladi-Salihu, gẹgẹ bi abẹnugọn ile igbimọ aṣofin kẹwaa naa lẹẹkeji.
 
AbdulRazaq ni oun nigbagbọ wi pe Ọnarebu Emmanuel Ojo Oyebọde ti wọn yan gẹgẹ bi igbakeji abẹnugọn yoo ṣe daadaa, ati pe yoo mu ile igbimọ naa tẹsiwaju
 
Bakan naa lo gba wọn lamọran lati ṣiṣẹ sin ipinlẹ Kwara nipa ifẹ, iṣọkan ati ifọwọsowọpọ wọn fun ilọsiwaju.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI