AbdulRazaq ki Gbajabiamila ati Akumẹ ku oriire ipo tuntun ti wọn yan wọn fun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 4, 2023

AbdulRazaq ki Gbajabiamila ati Akumẹ ku oriire ipo tuntun ti wọn yan wọn fun


Gomina AbdulRahman Abdulrazaq ti ipinlẹ Kwara ti ki olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin ana, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila ati Gomina tẹlẹri, George Akumẹ ku oriire ipo ti Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu yan wọn fun.

Aarẹ Tinubu lo kede Gbajabiamila gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ rẹ, to si tun kede Akumẹ gẹgẹ bi akọwe ijọba apapọ ti yoo ba a ṣiṣẹ ninu iṣakoso yii.

Ninu atẹjade ikini ti Gomina AbdulRazaq gbe jade lati ọwọ akọwe iroyin rẹ, Rafiu Ajakaye lo ti sọ pe ipo to tọ si awọn mejeeji ni Aarẹ yan wọn fun, to si loun nigbagbọ wi pe wọn yoo ṣe daadaa.

O l'awọn mejeeji ti ṣe daadaa sẹyin, wọn si ti ni iriri to ṣee gbẹkẹle lati ṣiṣẹ ti wọn gbe le wọn lọwọ.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe inu oun yoo dun lati ba awọn mejeeji ṣiṣẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Kwara ati gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ awọn gomina ni Naijiria.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI