Afeez Agoro, ọkunrin to ga julọ ni Naijiria jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 15, 2023

Afeez Agoro, ọkunrin to ga julọ ni Naijiria jade laye


Afeez Agoro Ọladimeji, ọkunrin to ja julọ lorileede Naijiria ti jade laye lẹni ọdun mejidinlaadọta, lẹyin aisan to kọluu lati bi oṣu meloo kan sẹyin.
 
Agoro lo ga niwọn bata ẹsẹ meje ati mẹrin (7 ft 4). Aisan kan to nii ṣe pẹlu ibadi ati ẹsẹ, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni hip arthritis ni wọn lo ṣe Agoro ko to di pe ọlọjọ de.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe niṣe ni wọn gbe Agoro digbadigba lọ si ọsibitu LUTH, Lagos University Teaching Hospital, nigba ti nnkan fẹẹ yiwọ nibi ti wọn ti n tọju ẹ.
 
Nnkan bi aago meje aabọ irọlẹ la gbọ pe ọkunrin naa da gbogbo tọwọ rẹ silẹ, to si gba ọrun alakeji lọ.
 
L'ọsẹ bii meloo kan sẹyin ni Agoro rawọ ẹbẹ s'awọn ẹlẹyinju ọmọ Naijiria fun iranwọ owo lati ṣiṣẹ abẹ lori aisan yii, ṣugbọn ti ko pada ri bo ṣe lero.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI