Aisan to ṣeku pa ọmọ mi lo gba dukia ati owo ti mo ni tẹlẹ lọwọ mi - Alapinni figbe ta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 24, 2023

Aisan to ṣeku pa ọmọ mi lo gba dukia ati owo ti mo ni tẹlẹ lọwọ mi - Alapinni figbe ta


Gbajugbaja agba oṣere tiata nni, Oloye Ganiu Nọfiu ti sọ pe aisan to ṣeku pa ọmọ oun lo gba mọto ati ọpọ dukia, ti fi mọ owo lọwọ oun.
 
Oloye Nọfiu ti ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye, paapaa awọn ololufẹ rẹ mọ si Alapinni lo sọrọ naa lori ikanni ayelujara laipẹ yii, to si n bẹbẹ pe k'awọn eeyan ṣiju aanu wo oun naa.
 
"Mọto meji ni mo ni tẹlẹ, ṣugbọn ti mo ta gbogbo rẹ nigba ti ọmọ mi ọkunrin dubulẹ aisan. O ba mi ninu jẹ nitori pe mo pada padanu ẹ."
 
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni awọn eeyan dide iranlọwọ fun agba oṣerebinrin nni, Iya Gbonkan, ti wọn si kọ ile, ti wọn tun ra mọto fun un.

Bakan naa ni awọn eeyan tun ra mọto fun Fatai Oodua ti awọn eeyan tun n pe nu Lalude.
 
Idi ree ti Alapinni naa fi jade sita wi pe k'awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ oun naa dide iranlọwọ foun, nitori pe oun naa nilo iranlọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI