Awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ni igbagbọ kikun ninu Dapọ Abiọdun lati yan awọn alabaṣiṣẹpọ to kaju oṣuwọn - Ajiki-Olu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 11, 2023

Awọn ọmọ ipinlẹ Ogun ni igbagbọ kikun ninu Dapọ Abiọdun lati yan awọn alabaṣiṣẹpọ to kaju oṣuwọn - Ajiki-Olu


Oluwo tiluu Ijẹja Abẹokuta ipinlẹ Ogun, Oloye Arẹmu Bamgboye ti ọpọ awọn eeyan mọ si Ajiki-Olu ti jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa ni igbagbọ kikun Gomina Dapọ Abiọdun, fun idi eyi, o sọ pe gomina naa yoo ṣe daadaa.

Ajiki-Olu, ẹni to jẹ gbajugbaja puromota olorin ati fiimu lo sọrọ naa lọjọ Aiku tii ṣe Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu kẹfa, ọdun ti a wa yii niluu Abẹokuta.

O sọrọ yii lati tako bi awọn kan ṣe n sọ pe Gomina Abiọdun ko tii yan awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ fun saa keji, lẹyin bi ọjọ meloo kan ti wọn ti bura fun un, fun saa keji yii.

Agba Oloye naa, Ajiki-Olu sọ pe Gomina Abiọdun ni lati farabalẹ wo awọn to tọ, ati awọn to yẹ fun ipo kọọkan ni, ko ma ba a ṣe aṣiṣe ti yoo koba a.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:

"Yiyan awọn alabaṣiṣẹpọ kii ṣe nnkan to ya bẹẹ, eeyan ko gbọdọ kanju lati yan awọn ti yoo mu iṣakoso rẹ tẹsiwaju, paapaa julọ nidi iṣejọba ipinlẹ.


"A ko le sọ pe bi nnkan ṣe n gbona la ṣe fẹẹ sare juu silẹ, rara, akoba nla ni yoo jẹ. Bi ẹ ba sọ pe awọn oju ti ẹ fẹran lẹ fẹ nipo, to si jẹ pe awọn oju naa ko yẹ fun ipo to wa lọkan yin, ipalara ni yoo jẹ.

"Dapọ Abiọdun mu ileri rẹ ṣẹ ni saa akọkọ, eyi lo jẹ k'awọn araalu tun ni igbagbọ wi pe yoo ṣe ju bẹẹ lọ ni saa keji, to mu ki wọn dibo fun un, paapaa julọ nigba ti ko si ẹni to tun kaju oṣuwọn lati dari ipinlẹ Ogun ninu eto idibo to kọja ju oun naa lọ.

"Bi ẹ ba wo Aarẹ Tinubu, ẹ maa rii pe oun naa ko tii yan awọn alabaṣiṣẹpọ minisita rẹ ti yoo ba a ṣiṣẹ pọ, o yẹ ko ti yee yin wi pe yiyan awọn alabaṣiṣẹpọ kii ṣe ohun ti wọn gbọdọ kanju si.

"Gomina Abiọdun ti ni iriri to pọ, idi ree to fi gbọdọ farabalẹ wo ibi to yẹ fun ẹnikọọkan lati di mu. Asiko ṣi wa, ẹni ti wọn ba si n gbe iyawo bọ wa ba kii garun.

"Ohun to da mi loju gidi ni pe Gomina ti mọ awọn to fẹẹ yan si ipo kọọkan, o kan tubọ nilo asiko diẹ ni, ati pe asiko ṣi wa rẹpẹtẹ. Saa keji yii yoo dara ju saa akọkọ lọ, mo ni imọlara yii, a si gbọdọ ni suuru to pọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI