Damọla Ọlatunji sọ idi ti ko fi sọrọ lori aarin oun ati Bukọla Arugba to daru - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 18, 2023

Damọla Ọlatunji sọ idi ti ko fi sọrọ lori aarin oun ati Bukọla Arugba to daru


Gbajugbaja oṣere tiata nni, Damọla Ọlatunji ti sọ pe nitori ifẹ toun ni si awọn ọmọ oun, lo fa a toun ko fi sọrọ lori iyapa to waye laaarin oun ati Bukọla Awoyẹmi, iyẹn Arugba to daru.

Damọla Ọlatunji lo sọrọ naa lonii, ọjọ Aiku tii ṣe Sannde lakoko to n ki ara rẹ fun ayajọ ọjọ awọn baba lagbaye.

Bẹ o ba gbagbe, inu oṣu karun-un, ọdun yii ni Bukọla Arugba kede sita lori ikanni ayelujara wi pe ko si ifẹ mọ laaarin oun ati Damọla Ọlatunji, ati pe awọn ko figba kan ṣe igbeyawo.

Arugba ṣalaye pe baba awọn ibeji oun lasan ni Damọla jẹ, tawọn si ti jọ tọwọ bọwe adehun lori bukata awọn ọmọ naa.

Damọla Ọlatunji nigba to n sọrọ lori fọnran oun atawọn ọmọ rẹ to gbe jade lori ikanni ayelujara ti Instagram sọ pe oun nifẹẹ wọn pupọ.

Ninu ọrọ rẹ, o ni;

"Ko sẹni to le ri omije ati ẹru ti baba maa n ni, ifẹ baba ko ṣee sọ, ṣugbọn itọju ati aabo rẹ jẹ opo ati okun ni gbogbo ọjọ aye awọn eso rẹ. Taiwo ati Kẹ̀hinde, aisọrọ nii ṣe pẹlu ifẹ ati ọwọ ti mo ni sii yin. ❤️❤️❤️❤️A ku ayajọ ọjọ awọn baba!"

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI