Ẹ fi Tinubu lọrun silẹ, ẹ jẹ ko ṣejọba rẹ - Ẹgbẹ Ọhanaeze Ndigbo gba Atiku ati Obi lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 12, 2023

Ẹ fi Tinubu lọrun silẹ, ẹ jẹ ko ṣejọba rẹ - Ẹgbẹ Ọhanaeze Ndigbo gba Atiku ati Obi lamọran


Bi awọn ọmọ Naijiria kaakiri agbaye ṣe n ṣayẹyẹ ayọjọ iṣejabọba awarawa, ti wọn si tun n ṣe iranti Oloogbe Mọshood Kaṣhimawo Ọlawale Abiọla kaakiri agbaye, ẹgbẹ kan ti wọn pe ara wọn ni Ohanaeze Ndigbo Socio-Cultural Organization ti gba oludije sipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar ati Peter Obi toun du ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour lamọran lati jawọ ninu ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn n pe lati tako idibo ọdun 2023 to gbe Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu wọle.


Ẹgbẹ Ohanaeze sọ pe ki wọn jawọ ninu ẹjọ naa, ki wọn si fi Aarẹ Tinubu lọrun silẹ lati ṣe ijọba rẹ, nitori pe asiko ti Naijiria nilo ifọwọsowọpọ ree.
 
Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ naa, Okechukwu Isiguzoro fi sita lo ti sọ pe ki Atiku ati Obi dide lati gbaruku ti iṣakoso Tinubu nipa imọ ati ọgbọn ti wọn ni, eyi ti yoo mu Naijiria tẹsiwaju.
 
Bẹẹ lo tun fi kun un pe ki Atiku ati Obi lo owo ti wọn n na ni kootu lati fi gbaruku ti iṣakoso Tinubu, ki wọn si jẹ ki ogun ti wọn dawọ le pari.

“Owo ti Atiku ati Peter Obi n na lati fi pe ẹjọ Tribunal, a bẹ ẹyin akikanju ọmọ Naijiria meji yii wi pe ki ẹ gbaruku ti Tinubu, nitori pe ogun ti pari.
 
“Ki wọn gbe imọ ati ọgbọn wọn kalẹ lati rii pe awọn ọmọ Naijiria ko tun koju iṣoro nla mọ.
 
“Ọrọ amọran iṣejọba awarawa ti a ni si Atiku, Peter Obi, ati awọn ọmọ Naijiria ti wọn ro pe awọn ni ẹtọ ti iwe ofin lati tako Tinubu nile ẹjọ Tribunal titi de ile ẹjọ agba orileede yii. Ki wọn jawọ ninu ẹjọ naa latari ifẹ ti wọn ni si orileede wọn.
 
“A mọ pe igbesẹ nla ti yoo mi wọn, awọn agbẹjọro ati awọn alatilẹyin wọn ree; ṣugbọn sibẹ nitori ifẹ ti wọn ni si Naijirai, ki wọn faaye gba alaafia, ki wọn si gbaruku ti Aarẹ to n fẹ ilọsiwaju ilu, ki orileede yii le maa pese awọn ohun to yẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI