Ẹ jẹ ki ileeṣẹ eto Aṣa da duro lorileede Naijiria - Baba Aṣa agbaye pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 18, 2023

Ẹ jẹ ki ileeṣẹ eto Aṣa da duro lorileede Naijiria - Baba Aṣa agbaye pariwo sita


Gbajugbaja olori eto Aṣa lagbaye, Oloye Joel Ọlaniyi Ọyatoye ti gba ijọba orileede Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu lamọran lati ya ileeṣẹ Aṣa sọtọ, to si ni ileeṣẹ naa to lati da duro.
 
Oloye Ọyatọye lo sọrọ yii nibi ipade to ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn akọroyin Yoruba lorileede Naijiria, ti a mọ si League of Yoruba Media Practitioners (LYMP), eyi to waye n'ipinlẹ Ekoo laipẹ yii.

Bẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ eto iroyin ati aṣa, iyẹn Ministry Of Information and Culture lo wa loju kan naa, to si jẹ pe minisita kan ṣoṣo lo n ṣakoso mejeeji ni Naijiria.
 
Oloye Ọyatoye to n jẹ gbajugbaja ninu awọn ọmọ Yoruba to n karamaasiki aṣa ni Naijiria ati lorilẹ-ede Canada, jẹ ko di mimọ pe ko yẹ ko maa lọ bẹẹ rara, nitori pe ọtọọtọ ni, ko si jọ ara wọn.
 
Nibẹ lo ti sọ pe aṣa funra ẹ to lọtọ lati da duro ko si gbe ọrọ aje orilẹ-ede soke, ju bo ṣe jẹ pe eto iroyin nikan nijọba n fun lanfaani ati akiyesi to pọ julọ lorilẹ-ede wa.

Oloye Ọyaniyi tawọn eeyan mọ si Baba Aṣa sọrọ pẹlu alaye pe b'ijọba orilẹ-ede yii ṣe n pin aṣa mọ eto iroyin ko daa to, nitori aṣa funra ẹ kẹnu pupọ pẹlu awọn ẹka to pawo fun idagbasoke orilẹ-ede. O ni ṣugbọn o ṣe ni laanu pe Naijiria ko ṣe tiẹ bẹẹ yẹn.

Oloye Ọyatoye to maa n tẹ pẹpẹ ayẹyẹ Aṣa Day lọdọọdun nilẹ yii ati ni Canada fi kun un pe awọn orilẹ-ede mi-in wa to jẹ wọn ko ni nnkan meji ti wọn fi n ṣe ọrọ aje ju aṣa wọn lọ, nibi kawọn eeyan maa rin irin ajo afẹ waa wo wọn ni wọn ti n rowo ṣelu, wọn o si kẹrẹ laarin ẹgbẹ wọn, ka ma ti i sọ Naijiria t’Eledumare fi nnkan aṣa rẹpẹtẹ jinnki lati ẹya kan si ikeji. Eyi ti Yoruba nikan si da ni ninu ẹ ko ṣee da ọwọ bọ ni Baba Aṣa wa.

“Ni Canada ti mo n gbe, mo niṣẹ gidi lọwọ ti wọn n sanwo to daa fun mi, ẹkọ nipa ofin ni mo kọ nileewe. Ṣugbọn nitori ifẹ aṣa Yoruba ti mo fẹẹ fi han wọn han lọhun-un ati kari aye, mo kọwe fiṣẹ naa silẹ, mo bẹrẹ si i ṣe gbogbo nnkan aṣa, mo ṣi ile iṣẹmbaye si Canada, mo kọwe sijọba wọn mo si n ṣe e lọ.

“Titi doni, mi o kabamọ rẹ, ebi o pa mi,aṣiri mi ko si tu pẹlu bo ṣe jẹ pe mi o ri iranlọwọ owo lati ọdọ wọn to. Ti emi ti mo jẹ ẹnikan ṣoṣo ba le ṣe aṣeyọri bẹẹ latọdun ti mo ti kọwe fiṣẹ silẹ, ki lohun to de tijọba ko le jẹ ki minisiri aṣa da duro ni Naijiria yii.

“Aṣa yoo pawo idagbasoke fun ilẹ wa lai pẹ rara, lai mu wahala wa si ni. Ṣugbọn bawo leyi yoo ṣe waye nigba to ba jẹ ẹka iroyin ti wọn mu mọ ọn ni wọn n runwo si ju lọ.

“Ọba to jokoo lori itẹ, aṣa ni, ọpa aṣẹ rẹ to mu da ni, aṣa ni, ṣugbọn tẹ ẹ ba lọọ ba wọn pe ki wọn ran yin lọwọ lati gbe aṣa ga, ki i ya wọn lara. Ohun to ṣẹlẹ labala ẹyin tẹ ẹ jẹ akọroyin ledee Yoruba naa ree, to jẹ bijọba atawọn ọba ba fẹẹ ṣayẹyẹ to kan yin gbọngbọn, awọn akọroyin lede oyinbo ni wọn yoo tun maa wa kiri. Eyi ko yẹ ko ri bẹẹ, ko yẹ ka ya ẹni abi wọn mọ ki i wu wọn, ka yee ṣe bii ẹni tẹni ẹlẹni n ya lara.

“Bẹ ẹ ri ọba Yoruba mi-in lode, oun ni yoo kọkọ nawọ sawọn eeyan to yẹ ki wọn dọbalẹ ki i, ọba ti funra ẹ tẹ aṣa mọlẹ nitori ohun to fẹẹ gba lọwọ awọn to pe e sode, gbogbo eyi ko pọn Yoruba le, ko daa fun aṣa wa.

“Ti mo ba fẹẹ patẹ aṣa ni Canada, wọn ki i di mi lọwọ, ijọba wọn yoo gba mi tọwọ-tẹsẹ ni bi wọn o tiẹ fun mi lowo, ṣugbọn ni Naijiria nibi, bẹ ẹ fẹẹ ri gomina nitori ipatẹ aṣa, wọn o ni i jẹ ka ri wọn, gbogbo eyi lo n fa ina aṣa to n ku, to n ko ba ede ati awọn iṣe wa.

“Tijọba ba ya minisiri aṣa sọtọ, ti wọn fi awọn eeyan ti wọn mọ nipa ẹ ti wọn ko si tori owo ṣe e sibẹ, wọn yoo ri i pe idagbasoke ọrọ aje yoo waye kia ju bi wọn ṣe n pin ‘Culture mọ Information’ lọ. Dandan kọ ni ki minista wa lọtọ fun Culture, wọn le yan alaboojuto aṣa nikan fun un bi wọn ba yan minista iroyin tan, ki wọn waa wo o boya eeyan aa maa jẹ ọba kiya jẹ ẹ, boya awọn on-nilẹ ko ni i maa gbọ bukaata ju tiṣaaju lọ’’

Bẹẹ ni Oloye Joel Ọlaniyi Ọyatoye (Baba Aṣa) wi.

Lasiko yii to si waa jẹ pe aarẹ Yoruba lo wa lori aleefa ni Naijiria, Baba Aṣa ṣalaye pe igbagbọ wa pe iyatọ yoo wa ninu bawọn eeyan wa ṣe n fọwọ yẹpẹrẹ mu aṣa, eyi naa lo si fa a to fi jẹ pe ayẹyẹ Aṣa Day tọdun yii yoo waye niluu Abuja ti i ṣe olu-olu Naijiria, ko le baa ṣoju Aarẹ Bọla Tinubu gan-an.

Ki iyatọ si le wa si tawọn ijọba atijọ ti wọn ki i ṣe elede wa. Ipari oṣu kẹsan-an ni ti United Kingdom, yoo waye ni Canada pẹlu ki wọn too pada wale s’Abuja lati ṣe tiwa bi Baba Aṣa ṣe sọ.
 
Kayegbọ

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI