June 12: AbdulRazaq ni k'awọn ọmọ Naijiria gbaruku ti Tinubu fun iṣejọba tiwa-n-tiwa alailẹgbẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 12, 2023

June 12: AbdulRazaq ni k'awọn ọmọ Naijiria gbaruku ti Tinubu fun iṣejọba tiwa-n-tiwa alailẹgbẹ


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti ipinlẹ Kwara ti gba gbogbo ọmọ orileede Naijiria patapata lamọran lati gbaruku ti Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu fun iṣejọba tiwa-n-tiwa alailẹgbẹ.
 
AbdulRazaq, ẹni to tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn gomina ilẹ Naijiria lo sọrọ yii ninu ọrọ rẹ fun ti ayajọ iranti ọjọ iṣẹjọba tiwa-n-tiwa to waye lonii, ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 2023.
 
Onii lo pe ọgbọn ọdun ti awọn ọmọ Naijiria jade lati dibo yan ẹni ti wọn n fẹ lati ṣoju wọn, iyẹn Oloogbe Mọshoos Kaṣhimawo Ọlawale Abiọla gẹgẹ bi aarẹ, ṣugbọn ti ijọba ologun pada da ibo ọhun nu.
 
O ni ohun to ṣẹlẹ lọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1993 lọhun lo bi eyi ti a n ṣe iranti rẹ lonii, nitori pe ireti ti ọpọ n reti nigba naa ko wa si imuṣẹ, to si ni gbogbo ireti naa lo ti pada ji dide bayii, ti Aarẹ Tinubu ti n mu wa.
 
Siwaju sii lo sọ pe ọna kan ṣoṣo lati maa ṣe iranti awọn akọni eto iṣejọba tiwa-n-tiwa ni lati fi ara jin sinu imọ ati ọgbọn lati ji eto iṣejọba awa-arawa dide nipa fifọwọsowọpọ lati kọ orileede ti yoo duro ṣinṣin nipa itara.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI