O ma ṣe o! Wọn ṣa Dasọla, akẹkọọ Poli l’Ondo pa, wọn tun yọ ẹyinju rẹ lọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 17, 2023

O ma ṣe o! Wọn ṣa Dasọla, akẹkọọ Poli l’Ondo pa, wọn tun yọ ẹyinju rẹ lọ


Ọjọ buruku, eṣu gbomimu l’ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii jẹ niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, nigba ti wọn ba oku akẹkọọbinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Dasọla ninu yara rẹ, pẹlu ọgbẹ ada ti wọn ṣa a.

Akẹkọọ ile-ẹkọ gbogboniṣe ti Adeṣeun Ogundoyin to wa niluu Eruwa, ipinlẹ Ondo ni wọn pe Dasọla, ẹni ti wọn loo wa ni ipele keji, ẹka ikẹkọọ iṣẹ iroyin ati igbohunsafẹfẹ (Mass Communication) nile ẹkọ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn sọ pe ọkan lara awọn Dasọla ti a fi orukọ bo laṣiri lo ṣakiyesi pe awọn ko rii ninu yara idanwo ti wọn ṣe l’Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, to si gbiyanju lati pe ẹrọ ibanisọrọ rẹ.

Wọn ni ko sẹni to gbe ẹrọ ibanisọrọ rẹ, eyi lo ṣe e ni kayeefi, to fi gba ile Dasọla to wa ladugbo Ile Idibo lọ. Igba to de bẹ, ni wọn lo ba kọkọrọ lẹnu ilẹkun, eyi to fi han daju pe ko si nile.

Ọjọ Furiadee, ana ni wọn sọ pe awọn ara adugbo ti Dasọla n gbe bẹrẹ sii gboorun buruku, ti wọn si ṣakiyesi pe lati inu yara Dasọla ni oorun buruku naa ti n jade.

Lara awọn to f’iṣẹlẹ ọhun to wa leti ṣalaye pe bi awọn ara adugbo ṣe yọju lati oju ferese wọnu yara Dasọla, lo jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ba oku rẹ lori ibusun pẹlu ọgbẹ ada lara, ti wọn tun ti yọ ẹyinju rẹ lọ.

Eyi lo mu ki wọn f’igbe ta, ti wọn si jẹ k’awọn ara adugbo mọ ohun to n ṣẹlẹ. Loju ẹsẹ nibẹ ni wọn l’awọn agbaagba adugbo ti ranṣẹ s’awọn ọlọpaa ẹkun Eruwa lati wa wo ohun ti oju wọn ri.

Ko tan sibẹ, a gbọ pe awọn akẹkọọ to wa lagbegbe yii tun fi iṣẹlẹ naa to awọn alaṣẹ ile-ẹkọ gbogboniṣe wọn leti, ti awọn aṣoju naa si debẹ lati foju wọn rii.

Nipa iranlọwọ awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn fi gbe oku Dasọla lọ si ọsibitu ijọba tiluu Eruwa lati ṣayẹwo iru iku to pa a.

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la gbọ pe iwadii awọn ọlọpaa ti bẹrẹ, pẹlu ileri wi pe awọn yoo wọ awọn amookunṣeka naa to mọ nipa iku Dasọla sita lati foju wọn han gbogbo agbaye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI