Ọrọ buruku ti wọn n sọ si mi ko kan mi, idẹra awọn eeyan mi lo jẹ mi logun - Gbenga Daniel - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 30, 2023

Ọrọ buruku ti wọn n sọ si mi ko kan mi, idẹra awọn eeyan mi lo jẹ mi logun - Gbenga Daniel


Gomina ipinlẹ Ogun tẹlẹ, to n ṣoju ẹkun idibo Ila Oorun ipinlẹ Ogun (Ogun East) nile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Ọtunba Gbenga Daniel ti ṣalaye pe ẹsun ti awọn kan fi n kan oun ati ọrọ kobakungbe ti wọn n wi kiri ko tu iru kan lara oun, o ni ohun to jẹ oun logun lọwọ yii ni bi igbesi aye irọrun fun awọn eeyan agbegbe toun n ṣoju fun. 

Ọtunba Gbenga Daniel sọrọ yii nibi ipade apero kan ti ẹgbẹ awọn akọroyin lede Yoruba taa mọ si League of Yoruba Media Practitioners, LYMP, ṣe pẹlu wọn ni alẹ ana Mọnde lori ẹrọ ayelujara.

Bẹẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Gbenga Daniel sọ ninu ifọrọwerọ fun awọn oniroyin pe ohun to fa ija laarin oun ati Dapọ Abiọdun to jẹ gomina ipinlẹ Ogun ni bi oun ṣe pinnu lati ṣiṣẹ fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu fun ipo Aarẹ ilẹ wa, dipo Igbakeji Aarẹ igba naa; Yẹmi Ọṣinbajo ti Abiọdun n ṣiṣẹ fun. 

Daniel tun sọ ninu ifọrọwerọ naa pe oriṣiiriṣii ihalẹ ati idunkooko mọ ni loun dojukọ lasiko naa ninu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ogun lasiko yii nitori bi oun ṣe to sẹyin Tinubu lati di Aarẹ ilẹ wa. 

Amọ ṣa, ọrọ ti Gbenga Daniel sọ yii ko dun mọ ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ogun ninu, wọn ni Ọtunba Gbenga Daniel ti gbogbo eeyan tun mọ si OGD ko fi igba kankan ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bọla Tinubu.  

Ninu ọrọ ti igbakeji alukoro ẹgbẹ naa, Oluṣọla Ogunsanya, sọ fun awọn oniroyin, o ni ohun ti Gbenga Daniel sọ fun awọn oniroyin naa, irọ funfun balau gbaa ni. O ni, ẹgbẹ oṣelu PDP ni OGD ṣe atilẹyin fun lasiko ibo naa, ati pe ọpẹlọpẹ Gomina Dapọ Abiọdun to gba Daniel lọwọ iṣubu, iba ti parun si oko igbagbe patapata ninu oṣelu. 

Ṣugbọn, nigba ti Gbenga Daniel n ba awọn oniroyin lede Yoruba, taa mọ si League of Yoruba Media Practitioners, sọrọ, o ni gbogbo ọrọ ti wọn n sọ si oun ko tun iru kankan, bẹẹ loun si ti gba gbogbo rẹ mọra patapata. 

O ni: "Agba maa n gba naa ni, eyi ti wọn ba sọ pe mo ṣe, bẹẹ naa lori, eyi to ṣe patako ni bi a ṣe maa ran awọn araalu lọwọ, ebi n pa awọn eeyan, ara n ni wọn, mo si n gba a ladura pe eyi ti wọn ni ki n lọọ ṣe, Ọlọrun a fun mi lokun ati agbara lati ṣe e, bẹẹ lo si maa ri i. 

"Mo fẹẹ fi ye awọn eeyan pe ko si nnkan ti mo n le, ko si nnkan to n le mi, Ọlọrun ṣe daadaa fun mi lati kekere, ko si nnkan to wa ti mo n le ju pe ka fi ilu wa silẹ ju bi a ṣe ba a. Nigba ti mo jẹ gomina, a ṣe iwọn ti a le ṣe, awọn to n ṣe e lọwọ naa, nigba ti wọn ba ṣetan, awọn mi in naa a tun gbe e lati ibẹ lọ siwaju, bo ṣe ri niyẹn."
      

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI