Ọwọ Amọtẹkun tẹ Taiwo, ogbolobo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n wa tipẹ l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 15, 2023

Ọwọ Amọtẹkun tẹ Taiwo, ogbolobo ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn n wa tipẹ l'Ọṣun


Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba ti a mọ si Amọtẹkun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin, ọmọ ọdun mọkandinlọgbọn kan, Taiwo Ogunṣọla, ẹni ti wọn lawọn ti n wa tipẹ.
 
Ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun paraku ni wọn pe Taiwo, ẹni ti wọn lo ti pẹ ti wọn ti n wa lori ẹsun iwa ẹgbẹ okunkun ti wọn fi kan an.
 
Agbegbe Olomilagbala to wa niluu Ileṣa, ipinlẹ Ọṣun la gbọ pe ọwọ ti tẹ Taiwo laipẹ yii. Wọn ni awọn kan lo ta ileeṣẹ eleto aabo Amọtẹkun lolobo, ti wọn fi lọ gbe e.

Ọga agba naa, Bashir Adewinmbi ninu ọrọ rẹ sọ pe Taiwo ti jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ paraku loun, ati pe ibọn ilewọ ati aake lawọnn gba lọwọ ẹ ni kete t'ọwọ palaba ẹ segi.
 
Bẹẹ lo sọ pe awọn ti fa a le awọn ọlọpaa lati tẹsiwaju iwadii wọn, ko to di pe wọn foju ẹ ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI