Wọn dajọ iku fun gbajumọ Baale l'Ondo, ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan an - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 27, 2023

Wọn dajọ iku fun gbajumọ Baale l'Ondo, ẹsun ipaniyan ni wọn fi kan an


Ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ Ondo ti paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun Baalẹ ilu kan, Ojo Kọmọlafẹ, ẹni ọdun mejidinlọgọrin, lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an l'ọdun 2021.
 
A gbọ pe oludasilẹ ile-ẹkọ kan, Taofik Babalọla, ni wọn sọ pe Ojo lọwọ ninu iku ẹ lagbegbe Kajọla, ijọba ibilẹ Odigbo l'ọjọ keje, oṣu kẹjọ, ọdun 2021.
 
Agbefọba to fẹsun kan Ojo, H.M. Falowo, ni wọn lo pe ẹẹrii mẹrin ọtọọtọ to tako o niwaju ile-ẹjọ. Lara wọn si ni iyawo oloogbe, ọkan lara awọn araadugbo, ọlọpaa ati dọkita.
 
Iyawo Ojo, Arabinrin Babalọla, nigba to n sọrọ niwaju Onidajọ Yẹmi Fasanmi sọ pe inu yara loun wa lọjọ naa, nigba toun gburo ibọn to dun, to si loun sare jade lati wọ nnkan to n ṣẹlẹ.
 
Obinrin naa ni iyalẹnu lo jẹ foun nigba toun ri Falọwọ nigba to n jade ninu yara ọkọ oun pẹlu ibọn lọwọ, to si lẹru to ba oun lo jẹ koun na papa bora.
 
Siwaju sii lo sọ pe nigba to ṣe diẹ loun lọ wo ọkọ oun ninu yara rẹ, to si lo jẹ iyalẹnu nigba toun ba ọkọ oun inu agbara ẹjẹ lori bẹẹdi, to n kerora wi pe Kọmọlafẹ lo yinbọn foun.
 
O loju ẹsẹ loun ti sa jade sita lati ke gbajare sawọn ara adugbo lati dide iranlọwọ foun. Bẹẹ lo ni ibi t'awọn ti n duu lo ti dakẹ.
 
Bo tilẹ jẹ pe Kọmọlafẹ sọ pe irọ ni gbogbo ẹsun naa, o ni awọno kan lo sọ pe ki iyawo oloogbe yii yi ọrọ naa mọ oun lori, nitori toun ko mọ nnkankan nipa ẹ.
 
Nigba to n ggbe idajọ kalẹ, Onidajọ Fasanmi sọ pe awijare lasan ni Kọmọlafẹ n sọ, nitori pe ọrọ rẹ ko lẹsẹ nilẹ, to si paṣẹ pe ki wọn lọ yẹgi fun un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI