Mi o mọ pe ina maa pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ mi - Ṣaka, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye jẹwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, July 19, 2023

Mi o mọ pe ina maa pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ mi - Ṣaka, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye jẹwọ


Bi gendekunrin, ẹni ọdun mejilelogun tọwọ tẹ lori ẹsun ṣiṣe ẹgbẹ okunkun ṣe n dọbalẹ, bẹẹ naa lo n rababa, to si n bẹbẹ pe iṣẹ eṣu ni, ati pe oun yoo f'ẹgbẹ naa silẹ.
 
Laipẹ yii lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun tẹ Saka Wale, ẹni ti wọn sọ pe ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ni lagbegbe Ogijo, ipinlẹ naa.
 
Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn n gbogun ti iwa ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, iyẹn Anti Cultism lo rọwọ to Saka lagbegbe toun pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ fẹẹ lọ da wahala sile.
 
A gbọ pe Saka wa lara awọn ti kii gba alaafia laaye lagbegbe Ogijo, pẹlu boun ati awọn ẹmẹwa rẹ ṣe n fojoojumọ koju ija s'awọn alatako wọn.
 
Ni kete tọwọ tẹ Saka, o sọ pe ki wọn f'oju aanu wo oun, nitori toun ko mọ pe omi maa pada dilẹ lẹyin asunṣujẹ oun, ati pe oun ṣetan lati f'ẹgbẹ naa silẹ.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla jẹ ko di mimọ pe Saka ti jẹwọ to pọ f'awọn, to si lo di dandan k'awọnn foju rẹ ba ile-ẹjọ laipẹ, lẹyin ti gbogbo iwadii awọn ba pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI