Wọn ti pada gba beeli TrinityGuy ooooo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 22, 2023

Wọn ti pada gba beeli TrinityGuy ooooo


Iroyin to tẹ wa lọwọ ti jẹ ko di mimọ pe wọn ti pada gba beeli gbajumọ oṣere apanilẹrin ori ayelujara ti a mọ si skit nni, Abdullahi Adisa ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si TrinityGuy kuro lẹwọn to wa.
 
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, ọdun ti a wa yii ile ni Onidajọ P. O Adetuyibi ti ile ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Iyaganku niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ sọ pe ki wọn ṣi lọ fi Abdullahi pamọ s'ọgba ẹwọn Agodi, titi d'igba ti igbẹjọ miran yoo tun pada waye.

Ṣugbọn ninu fọto ti ọkan lara awọn akẹgbẹ TrinityGuy, iyẹn Cute Abiọla gbe jade soju opo fesibooku rẹ laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe ọkunrin naa ti gba itusilẹ.

Cute Abiọla lo jẹ ka mọ pe gbogbo igba ni TrinityGuy fi n gbadura l'ẹwọn ti wọn fi pamọ si, lori ko le ri aanu gba lati jade, ṣugbọn ti adura naa pada gba.No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI