Idanwo 'Common Entrance' yoo waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 8, 2023

Idanwo 'Common Entrance' yoo waye lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ ni Kwara


Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede sita gbangba wi pe idanwọ aṣewọle sile ẹkọ girama, eyi ti wọn n pe ni Common Entrance yoo waye kaakiri ipinlẹ naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Ninu atẹjade ti akọwe iroyin nileeṣẹ to n ri sọrọ eto ẹkọ n'ipinlẹ naa, Peter Amọgbọnjaye fi sita laipẹ yii lo ti sọ pe idanwo naa yoo bẹrẹ lati agogo mẹjọ aarọ.
 
O ni kaakiri ile-ẹkọ girama to wa ni ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to so Kwara papọ ni idanwo naa yoo ti waye lọjọ Abamẹta tii ṣe Satide naa.
 
Siwaju si i ni wọn sọ pe ọfẹ ni idanwo yii, nitori pe ijọba Kwara ti san gbogbo owo to yẹ, akẹkọọ kankan tabi obi kankan ko si gbọdọ san owo fun ẹnikẹni.
 
Bẹẹ ni wọn gba awọn alabojuto ati ọga ile-ẹkọ kaakiri n'imọran lati yago fun gbigba owo ailẹtọọ lọwọ awọn akẹkọọ tabi obi wọn, ati pe ẹni tọwọ ba tẹ lori iwa ọhun yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.

Bakan naa ni wọn tun gba awọn akẹkọọ lamọran lati ma ṣe gbiyanju iwa magomago lakoko idanwo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI