Ijọba Kwara ṣi ikanni ayelujara t'awọn akẹkọọ yoo ti jẹ anfaani owo iranwọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 8, 2023

Ijọba Kwara ṣi ikanni ayelujara t'awọn akẹkọọ yoo ti jẹ anfaani owo iranwọ


Ijọba ipinlẹ Kwara ti sọ pe awọn ti ṣi ikanni ayelujara ti gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ naa yoo ti jẹ anfaani owo iranwo lati mu ẹdinku ba iṣoro ti wọn n koju, paapaa lori owo iranwọ ori epo tijọba apapọ yọ.
 
Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ijọba Kwara kede wi pe awọn yoo bẹrẹ sii san owo fun gbogbo awọn akẹọọ, paapaa awọn to ti wa ni ipele aṣekagba gẹgẹ bi owo iranwọ.
 
Ni bayii, wọn ti wa sọ pe akẹkọọ to ba fẹẹ jẹ anfaani ninu owo iranwọ yii gbọdọ fi orukọ silẹ lori ikanni ayelujara ti wọn ṣẹṣẹ ṣi naa, lati le ni akọsilẹ wọn.
 
Eto ifọrukọsilẹ naa la gbọ pe yoo bẹrẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ titi di aago mejila oru, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun ti a wa yii.


Ki i ṣe gbogbo akẹkọọ ti wọn wa ni ipinlẹ Kwara nikan ni yoo jẹ anfaani yii o, gẹgẹ bi ijọba ṣe ṣalaye. Wọn ni awọn akẹkọọ ti wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ naa l'awọn ile-ẹkọ giga to jẹ ti ijọba kaakiri ipinlẹ naa nikan ni.
 
REGISTRATION PROCEDURE
1. Prospective students to visit the link https://scholarship.kw.gov.ng/palliative
2. Click on “Students' palliative ” link to Register your bio-data on the platform to obtain login details.
3. Verification through the registered email address provided on the platform
4. Use your login details with your password to fill the application form online.
5. Scan and upload the following documents online (mandatory).
• Recent Passport size photograph.
• Citizenship Certificate.
• Your Admission Letter.
• Your Institutional Valid I.D Card.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI