Lekan Adeniran di akọwe iroyin Gomina Abiọdun l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 17, 2023

Lekan Adeniran di akọwe iroyin Gomina Abiọdun l'Ogun


Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun ti kede gbajugbaja ati ogbontarigi akọroyin, Ọgbẹni Lekan Adeniran gẹgẹ bi akọwe iroyin ti yoo ba a ṣiṣẹ fun saa iṣakoso rẹ keji to n lọ lọwọ yii 

Ninu atẹjade ti akọwe ijọba, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi fi sita lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lo ti sọ pe iṣẹ Ọgbẹni Adeniran bẹrẹ loju ẹsẹ.

Adeniran, gẹgẹ bi a ṣe gbọ kẹkọọ nipa imọ eto ikansira-ẹni ati igbohunsafẹfẹ ti a mọ si Mass Communication, to si ni imọ kikun nipa iṣẹ naa fun bii ọgbọn ọdun le diẹ.

Ileeṣẹ iwe iroyin The Guardian ni Adeniran ti bẹrẹ iṣẹ iroyin rẹ lọdun 1992, nibi to ti ṣiṣẹ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP), ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ekoo.

Ọdun 2001 lo kuro ni The Guardian lati darapọ mọ ileeṣẹ iwe iroyin ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ nigba naa, iyẹn Daily Independent.

Akọwe iroyin tuntun yii tun ṣiṣẹ pẹlu awọn iwe iroyin miran bii Compass, Next ati National Mirror, ko to lọ darapọ WesternPost

Ileeṣẹ iwe iroyin WesternPost ni Adeniran ti di olootu, ko to di pe Gomina Abiọdun kede rẹ gẹgẹ bi akọwe iroyin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI