NIPR: AbdulRazaq ṣatilẹyin fun Saudat Abdulbaqi fun ipo ọmọ igbimọ alakoso - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, August 24, 2023

NIPR: AbdulRazaq ṣatilẹyin fun Saudat Abdulbaqi fun ipo ọmọ igbimọ alakoso


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti rawọ ẹbẹ si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ Nigerian Institute of Public Relations (NIPR) lati dide dibo fun ọkan lara awọn ọmọ ipinlẹ Kwara pataki, Ọmọwe Saudat Salah AbdulBaqi gẹgẹ bi ọmoọ igbimọ ẹgbẹ naa.
 
AbdulRazaq rawọ ẹbẹ yii, to si ni ki wọn dide dibo fun Ọmọwe AbdulBaqi ninu ipade gbogboogbo wọn to bẹrẹ lọjọ kẹtalelogun si ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 2023.

O ni latigba toun ti mọ Ọmọwe AbdulBaqi, iwa ọmọluabi lara ẹ, o si n gbe ogo ipinlẹ naa ga, nipa imọ iṣẹ to kọ, to si ka nileewe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI