Ọkọ baluu agberapa jabọ loju ofurufu l'Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, August 1, 2023

Ọkọ baluu agberapa jabọ loju ofurufu l'Ekoo


Niṣe lọrọ di boolọ o yago lọna lonii, ọjọ kinni, oṣu kẹjọ, ọdun 2023 nigba ti ọkọ baluu agberapa (Helicopter) deedee ja lulẹ lati oju ofurufu, to si ko ibẹrubojo b'awọn araalu.
 
Agbegbe ti wọn pe ni Ọba Akran, Ikẹja, ipinlẹ Ekoo ni ọkọ baluu naa ti ja lulẹ lojiji, iyẹn ni nnkan bi aago mẹta aabọ ọsan.
 
Inu ile kan to wa ni adojukọ ile epo AP Filling Station, ati ile ifowopamọ United Bank For Africa, UBA ni ọkọ baluu agberapa naa ja le.
 
Asiko ti wọn lo ku di]ẹ ko balẹ ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed International Airport (MMIA), lo gbina lojiji, to si jabọ lulẹ.
 
Awọn to wa lagbegbe yii la gbọ pe wọn sare gbiyanju lati doola ẹmi ẹni to wa ọkọ ofurufu agberapa naa, bo tilẹ jẹ pe a ko gbọ boya awọn eeyan miran wa ninu ẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn oṣiṣẹ to n ri sọrọ iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Ekoo, National Emergency Management Agency (NEMA) sare debẹ fun iranwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI