Ẹ gba wa lọwọ ayederu Baalẹ l'Eredo - Awọn araalu rawọ ẹbẹ si Alake ilẹ Ẹgba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, September 23, 2023

Ẹ gba wa lọwọ ayederu Baalẹ l'Eredo - Awọn araalu rawọ ẹbẹ si Alake ilẹ Ẹgba


"A o gba o, a o gba, ki Razaq jẹ Baalẹ wa l'Eredo o" ni orin ifẹhonu han ti ogunlọgọ awọn ọmọ ati olugbe ilu Eredo-Alaṣẹ to wa nitosi Ṣiun loju ọna marosẹ Abẹokuta si Ṣagamu, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun kọ wọ inu aafin Alakẹ ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ l'Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti n fẹhonu han lori ayederu Baalẹ kan ti wọn lo n gbogun ti wọn, iyẹn Razaq Amujara Ọladele.

Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, wọn ni Razaq kii ṣe ọmọ ilu Eredo-Alaṣẹ, ati pe awọn baba nla wọn lo fun baba-baba rẹ ni ilẹ lati fi da oko, ko to di pe wọn tun ta ilẹ fun un lati fi kọ ile si.
 
Lọdun mẹri sẹyin ni wọn sọ pe Razaq dide pẹlu awon aburo rẹ mẹrin lati sọ pe awọn fẹẹ gba ipo Baalẹ ilu naa to ṣofo lati bi ọdun meloo kan sẹyin, lati le maa ṣakoso ilu naa lọ.
 
Wọn ni Razaq ati awọn bii Dapọ Ọjẹrinde, Ṣọla Ọjẹrinde, Michael Ọjẹrinde, Sunday Ọjẹrinde ati Mope Ọjẹrinde ni wọn jọ gbe igbesẹ naa, lai jẹ k'awọn ojulowo ọmọ ilu.
 
Lẹyin ti wọn pari eto wọn la gbọ pe wọn lọ si ọdọ Olu tiluu Ṣiun, Ọba Lawrence Ọdẹyinka nibi ti wọn ti lọ purọ fun Kabiyesi wi pe ọmọ ilu l'awọn, wọn si nilo lati jẹ Baalẹ ti ipo rẹ ṣofo.
 
Bayii ni wọn sọ pe Kabiyesi ṣe ja ewe oye lee lori lati di Baalẹ, lai mọ pe omi yoa pada tẹyin wọ igbin lẹnu. Lakoko to n wuye naa, la gbọ pe o tun fi awọn aburo rẹ, to fi mọ sọfiyọ to n ba a ṣiṣẹ joye ilu.

Nibi ti wọn ti n fẹhonu han ni Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Gbadebọ ti sọ pe ki wọn lọ fi ọkan wọn balẹ nitori pe awọn yoo pe Razaq lati wa sọ tẹnu rẹ, lati le mọ igbesẹ ti wọn yoo gbe e.

Ọba Gbadebọ ni ki onikaluku wọn maa lọ sile pẹlu alaafia, ki wọn si gba alaafia laaye nitori pe niṣe ni ogun maa n tu ilu ka ni, ati pe oun yoo tun ba olu Ṣiun ṣe ipade lori ẹ.
 
Samson Adekunle Ajana nigba to n sọrọ, ṣalaye pe
"Ọmọ kan ti wọn fi jẹ Baalẹ le wa lori tipatipa kii ṣe ọmọ abule wa, Razaq Amujara Ọladele lorukọ ẹ lati inu mọlẹbi Ọjẹrinde lo si ti wa. Awọn aburo rẹ lo fi jẹ Baalẹ, ti wọn ko jẹ ki awa agbaagba ti a jẹ ojulowo ọmọ ilu mọ nipa ẹ.

"Abule keji to jẹ Itoku lo ti wa, ibẹ ni awọn Ọjẹrinde ti wa. Niṣe ni awọn baba wọn wa tọrọ ilẹ lọwọ wa ni. Awọn olori ẹbi wọn si mọ pe ipo Baalẹ ko tọ si wọn, nitori pe 'Iga' la fi n jẹ Baalẹ l'abule wa. Iga Adeniji, Iga Libẹgun ati Iga Ajana la fi n jẹ Baalẹ.

"Awọn Libẹgun ti jẹ Baalẹ, Awọn Adeniji ti jẹ, awa Ajana lo kan bayii. Awọn to ti jẹ sẹyin yii ti sọ pe awa lo kan. Ṣugbọn o jẹ iyalẹnu fun wa nigba ti a gbọ pe awọn mẹrin kan ko ara wọn jọ, wọn si lọ fi Razaq jẹ Baalẹ.


"Oriṣiriṣi iwa abuku lo n hu labule, bii ko maa ba gbogbo eeyan ja lai nidii, ko maa paṣẹ fun ojulowo ọmọ ilu nipa ohun ti wọn gbọdọ ṣe ati nnkan ti wọn ko gbọdọ ṣe, ko maa yinbọn, ko si maa ko tọọgi wọ abule.

"Kii ṣe ọmọ abule wa rara. A fẹ ki Kabiyesi, Alake ilẹ Ẹgba gba wa lọwọ Razaq, ki wọn ba wa yọ ọ danu, nitori pe kii ṣe ọmọ abule wa, a ko si fẹ n'ipo Baalẹ to n pe ara rẹ."

Titun Adeniji lati agboole Libẹgun ninu ọrọ tiẹ sọ pe 
"Baba baba mi lo tẹ abule Eredo Alaṣẹ do. Ko to di pe ọrọ Baalẹ yii yọju, a ti n ṣe ipade laaarin ara wa tipẹ. Igba ti Korona de, a f'opin si nitori pe ọna to jin la ti n wa. Awọn kan wa l'Ekoo, Abẹokuta ati bẹẹbẹẹlọ. Bi awọn ọmọ kan ṣe mu Razaq lọ sọdọ Kabiyesi, Olu tiluu Ṣiun lati fi jẹ Baalẹ.

"Kọbapẹ lo n gbe, iṣẹ agbero lo n ṣe. Igba ti a bẹrẹ ipade naa pada ni awọn kan sọ fun wa pe Razaq ti jẹ Baalẹ, a si sọ fun un loju ẹsẹ wi pe ko le ṣee ṣe, nitori pe ko tẹle ilana, ati pe kii ṣe ọmọ abule wa. Abule to ti wa lo lẹtọọ lati jẹ Baalẹ si.

"Ko si ẹnikankan to fun wọn ni aṣẹ. Ohun ti a fẹ bayii ni pe ki wọn ba wa yọ ọ ni Baalẹ abule. Awa agbaagba la ṣẹṣẹ maa jokoo lati fa eeyan kan kalẹ fun ipo Baalẹ. Ki Alake tete ba wa da sii.

Ọgbẹni Oluwatobi Bamidele, ọkan lara awọn ọmọ ilu naa sọ pe
"Beeyan ba sọ pe oun fẹẹ jẹ Baalẹ, o ni awọn ọna ati igbesẹ to gbọdọ tọ lati jẹ ẹ. Akọkọ ni pe agba ni wọn fi n ṣe e, ṣugbọn nigba ti aye ti laju bayii, éni to gbọdọ jẹ Baalẹ gbọdọ ni imọ iwe to kaju oṣuwọn, o kere julọ iwe mẹfa.

"Kiiṣe pe ki ọmọ garaaji kan de, ko loun jẹ Baalẹ, iwa tọọgi lo ma maa hu. Ẹlẹẹkeji ni pe o gbọdọ kọwe si abule to fẹẹ jẹ Baalẹ le lori, ki awọn agbaagba si ṣe iwadii nipa iru ẹni bẹẹ lati mọ idile to ti jade, ati iwe to ka, iriri rẹ ati bẹẹbẹẹlọ.

"Ko si gbogbo eyi. Ipa ni Razaq fi jẹ Baalẹ, ko mọ iwe kankan. Lotitọ, baba rẹ ni Baala ilu Igbore nigba to ti pẹ, gẹgẹ bi Ologboni. Razaq ati awọn aburo rẹ ni wọn jọ lọ s'ọdọ Olu Ṣiun lati sọ pe oun fẹẹ di Baalẹ, ti kabiyesi naa ko si ṣe iwadii ko to fi jẹ ẹ.

"Gbogbo awọn nnkan to n ṣe labule ni ko tẹ wa lọrun. O ti bẹrẹ sii ta ilẹ abule wa. Ko si ọna, o tun ti le awọn eeyan. Iwa tọọgi lo n hu si awọn araalu. Lẹyin to tun jẹ Baalẹ, gbogbo awọn mọlẹbi rẹ lo tun fi joye Balogun Ọtun, Osi ati bẹẹbẹẹlọ.

"O fi Dapọ Ọjẹrinde ṣe Ọtun ilu; Ṣọla Ọjẹrinde ni Balogun; Michael Ọjẹrinde ni Osi; Sunday Ọjẹrinde naa joye; Mope Ọjẹrinde ni Iyalaje ilu. Bakan naa lo tun fi ajoji, Lateef Iyana joye Babalaje. Ṣe awọn yooku ko lẹtọọ lati joye niluu ni, to jẹ pe awọn mọlẹbi rẹ nikan lo ko si ipo oye ilu.

"Nipa bẹẹ la ṣe wa bẹ Alake ilẹ Ẹgba wi pe ki wọn ba wa gbe igbesẹ lori ẹ, nitori pe Razaq Amujara Ọladele kii ṣe ọmọ abule wa, gbogbo awa ilu la si n sọ pe a ko fẹ ẹ gẹgẹ bii Baalẹ wa."

Razaq Ọladele ti wọn fi ẹsun kan

Bakan naa nigba to n sọrọ lẹyin ti Alake ilẹ Ẹgba ba wọn sọrọ tan, o ni Kabiyesi ti sọ pe awọn yoo ṣe iwadii rẹ

"Alake ti sọ fun wa pe ka lọ ṣe suuru, nitori pe wọn ko fẹ ija, ati pe wọn maa gbe igbesẹ to tọ ati eyi to yẹ lati ṣe nnkan letoleto, a si nigbagbọ pe Kabiyesi yoo ṣe ohun ti awa araalu n fẹ."

Sunday Ọlalekan Ọjẹrinde, ọkan lara awọn agba ninu ẹbi Ọjẹrinde ti Razaq ti jade nigba toun naa n sọrọ nibẹ sọ pe 
"Razaq ko lẹtọọ si ipo to gbe dani yẹn. Lotitọ ọmọ baba mi ni, ṣugbọn otitọ ọrọ ko le sọ pe ka sọ oun. Mo sọ fun nigba naa wi pe ipo Baalẹ ko tii kan wa. Mo kilọ fun un wi pe ilu Itoku la ti wa si Eredo, a kii ṣe ojulowo ọmọ Eredo. O ye mi lẹnu pe ko gbọ ọrọ si mi lẹnu.

"Libẹgun lo fun baba baba wa ni ilẹ ti wọn fi kọ ile si. Oye ko tii kan wa rara. Mo faramọ wi pe ki wọn Razaq kuro nipo to n pe ara rẹ. Mo jẹri pe wọn maa yọ ọ danu."

Nigba toun funra rẹ n tako awọn ẹsun ti wọn fi kan an, Razaq Ọladele sọ pe ija lo de ni orin di owe, nitori pe gbogbo awọn to n kaakiri lasiko yii lo mọ nipa boun ṣe di Baalẹ lọdun 2023.

O ṣalaye pe ọrọ owo lo da wahala silẹ, to fi di pe wọn bẹrẹ sii ba orukọ oun jẹ kaakiri, to si loun fẹran alaafia ati iṣọkan lo jẹ koun maa rawọ ẹbẹ lati ma ṣe jẹ ki ilu pin si meji.

Bakan naa lo fidi rẹ mulẹ pe lotito l'awọn kii ṣe ọmọ Eredo, ṣugbọn gẹgẹ bi ofin Naijiria to sọ pe beeyan ba ti lo ọdun mẹwaa ni agbegbe kan, o ti di ọmọ agbegbe naa niyẹn, to si ni ilu Eredo yii ni wọn bi baba oun si, ti wọn si tun bi oun sibẹ pẹlu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI