Ẹ wa gbọ aṣiri iku to pa Baba Fancy, igbakẹji ọga agba tẹlẹ nile-ẹkọ gbogboniṣe Mapoly - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, September 17, 2023

Ẹ wa gbọ aṣiri iku to pa Baba Fancy, igbakẹji ọga agba tẹlẹ nile-ẹkọ gbogboniṣe Mapoly


Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe igbakeji ọga agba tẹlẹ nile-ẹkọ gbogboniṣe ti Mọshood Abiọla to wa niluu, MAPOLY, Alagba Ọlalekan Sakibu Famuyiwa, ẹni ti ọpọ awọn eeyan mọ si Baba Fancy ti jade laye, ṣugbọn bi baba naa ṣe ku lo n ya awọn eeyan lẹnu.

Odu ni Baba Fancy jẹ, kii ṣaimọ f'oloko, paapaa nile ẹkọ gbogboniṣe ti Mapoly, ati kaakiri ipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ko pẹ ti baba naa jẹun ọsan tan nile ẹ to wa ladugbo Onikolobo niluu Abẹokuta, lo sun, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji lẹni ọdun mejilelaadọrin (72).

Wọn ni ounjẹ aladidun ni Baba Fancy jẹ tan, to fi wo o pe koun sun diẹ, lai mọ pe ọlọjọ ti de.

Igba to to asiko to yẹ ko ji dide, ti wọn ko gburo rẹ la gbọ pe wọn lọ wo o, to si jẹ pe ẹlẹmi ti gba a.

Loju ẹsẹ ni wọn sare gbe e digbadigba lọ si ọsibitu Redwood to wa lagbegbe Ibara GRA, ṣugbọn ti wọn sọ pe ẹpa ko boro mọ.

Olukọ imọ iṣoro, iyẹn Mathematics ati Statistics ni Oloogbe naa ni ẹka ikẹkọọ Science and Laboratory Technology; ibẹ lo wa ti wọn fi gbe e lọ si ẹka ikẹkọọ General Studies, nibi to ti di alakoso.

Ko pẹ lo tun di alakoso ẹka ikẹkọọ ile ẹkọ ikansira-ẹni ati iroyin igbalode, School of Communication and Information Technology.

Oloogbe naa tun jẹ alakoso ọrọ to nii ṣe pẹlu awọn akẹkọọ, Director of Students Affairs, nibi to ti pads di igbakeji ọga agba.

Siwaju sii lo tun jẹ alaga ẹgbẹ awọn olukọ nile ẹkọ gbogboniṣe, ẹka ti Mapoly, to si tun jẹ ọkan pataki lara awọn to da ẹgbẹ naa silẹ lorileede Naijiria, iyẹn Academic Staff Union of Polytechnic (ASUP).

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI