Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti f'oju gendekunrin, ẹni ọdun mẹrinlelogun nni, James Ovie, ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa niluu Okitipupa lọjọ Ẹti tii ṣe Furaide, ọsẹ ti a wa yii lori ẹsun ole jija ti wọn fi kan.
Ẹrọ igbalode ti wọn fi n gba ina sinu foonu, iyẹn 'Power Bank' to jẹ ti ileeṣẹ Oraimo ni wọn sọ pe James jigbe lọjọ kejidinlogun, oṣu keje, ọdun ti a wa yii.
Wọn ni nnkan bi aago mẹrin irọlẹ ni James lọ sinu ṣọọbu ẹni ti wọn pe ni Godwin Nwani to wa lagbegbe Ijokodo niluu Okitipupa, to si ji 'power bank' naa ti owo rẹ jẹ ẹgbẹrun marundinlogoji (N35,000) naira.
Agbefọba Zedekiah Orogbemi, nigba to n tako James niwaju adajọ sọ pe ẹsun naa tako iwe ofin ọdaran ipinlẹ Ondo tọdun 2006 ni abala Section 390 (9).
Onidajọ Cletus Ojuọla nigba to n sọrọ sọ pe anfaani wa fun James lati gba beeli ara rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ati oniduro kan ṣoṣo to le mu iwe ẹri owo ori ọdun meji to ti san silẹ, to si sun igbẹjọ siwaju di ọjọ kejilelogun, oṣu ti a wa yii.
No comments:
Post a Comment