Ọlọdẹ yinbọn fun araadugbo loju, niyẹn ba fọ loju nitori ọrọ ti ko to nnkan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 9, 2023

Ọlọdẹ yinbọn fun araadugbo loju, niyẹn ba fọ loju nitori ọrọ ti ko to nnkan


Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ko tii si aridaju wi pe awọn ọlọdẹ adugbo meji kan, Michael Adelayo ati Ganiyu Saka yoo bọ ninu iwa ọdaju ti wọn hu lọjọ keji, oṣu kẹsan, ọdun ti a wa yii.

Niṣe ni wọn lawọn mejeeji yii yinbọn fun ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ramọn Rasaq loju, ti oju rẹ si fọ danu loju ẹsẹ, eyi ti wọn lo jẹ kayeefi fun ọpọ awọn to gbọ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, wọn ni Ramon lo n bọ lati ibi to jade lọ, igba ti yoo fi de ẹnu ọna abawọle adugbo to n gbe, lo ṣakiyesi wi pe awọn ọlọdẹ to n duro sibẹ ti rin lọ.

Iri ree ti wọn lo fi ṣi geeti funra rẹ to wọnu ọgba adugbo lati maa lọ sile rẹ. Oju ọna ni wọn sọ pe awọn ọlọdẹ mejeeji ti pade rẹ, ti wọn si bẹrẹ sii beere bo ṣe wọle.

Nibi ti wọn lo ti n ṣalaye fun wọn la gbọ pe wọn ti sọ ọrọ naa di ija, ti wọn si bẹrẹ sii luu bi ole. Eyi lo fa a tiyẹn naa fi loun ko nii gba, to si koju wọn.

Wọn lojiji ni ọkan lara wọn fa ibọn yọ, to si yin in fun Ramọn loju, tiyẹn si ṣubu lulẹ loju ẹsẹ, to si bẹrẹ sii kerora.

Iro ibọn naa lo mu k'awọn araadugbo sare debẹ lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ, ti wọn si rii pe araadugbo ni yinbọn fun. Awọn to mọ ile Ramọn ni wọn sare lọ pe awọn eeyan rẹ nile lati fi to wọn leti.

Ẹgbọn Ramọn, Abiọdun Fatai lo gba teṣan ọlọpaa lọ lati fi to wọn leti, ti wọn loju ẹsẹ l'awọn ọlọpaa naa ti debẹ lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, to si jẹ iyalẹnu nigba ti ri iṣẹlẹ naa.

Wọn ko sọrọ ju ti wọn fi ko awọn mejeeji lọ teṣan lati fọrọ wa wọn lẹnu wo. Awọn ọlọpaa yii naa ni wọn ṣatọna bi wọn ṣe gba iwe ẹri ti wọn fi gbe Ramọn lọ si ọsibitu LUTH niluu Ekoo, iyẹn Lagos State University Teaching Hospital fun itọju to pe ye.
 
Ọmọlọla Odutọla nigba to n f'idi rẹ mulẹ ṣalaye pe awọn ọlọdẹ mejeeji yii ti wa lahamọ awọn, ati pe wọn ko ni pẹ ẹ foju ba ile-ẹjọ lori ẹsun igbiyanju lati paniyan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI