Owo ipolongo idibo tun da wahala silẹ laaarin Atiku ati Saraki - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 8, 2023

Owo ipolongo idibo tun da wahala silẹ laaarin Atiku ati Saraki


Bi iroyin to tẹ wa lọwọ ba fi jẹ otitọ, a jẹ pe ko ti sẹni to le yanju aawọ to wa laaarin oludije s'ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party (PDP) ninu eto idibo apapọ to kọja yii, Atiku Abubakar ati aarẹ ile igbimọ aṣofin agba orileede yi tẹlẹ, Bukọla Saraki.
 
Ko si nnkan meji ti wọn loo da wahla silẹ to kọja owo eto idibo ti wọn ni Atiku gbe silẹ ninu eto idibo to kọja yii, ṣugbọn ti wọn sọ pe Saraki ko gbe silẹ f'awọn ọmọ ẹgbẹ, eyi to fa ijakulẹ wọn n'ipinlẹ Kwara ninu eto idibo apapọ to waye l'oṣu keji ọdun yii.

Bẹ o ba gbagbe, ko pẹ ti eto idibo apapọ kọja kaakiri orileede Naijiria ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni Kwara bẹrẹ sii f'ẹsun kan Saraki wi pe ko wa ṣe akọsilẹ bo ṣe na owo eto idibo naa.

Olori ọdọ lẹgbẹ naa, Kọmureedi Dan Iya ti ṣe oriṣirisi afarahan lati jẹ ki gbogbo aye mọ bi igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ naa ṣe mu ẹgbẹ, to si ni wọn ko fi owo ba ẹgbẹ lo.
 
Kọmureedi Iya sọ pe awọn igbimọ amuṣẹya naa ko gbe owo kalẹ f'awọn ọmọ ẹgbẹ fun ipolongo ati awọn ohun ti wọn nilo lati fi jawe olubori.
 
O wa rawọ ẹbẹ si Sarari lati jade, ko si ṣalaye bo ṣe na owo ẹgbẹ naa, eyi to wa lati olu ile ẹgbẹ l'Abuja, ki awọn eeyan le mọ ohun to fa ijakulẹ wọn ninu eto idibo to kọja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI