Ọwọ tẹ Michael Jackson, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Ọta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, September 9, 2023

Ọwọ tẹ Michael Jackson, ogbologbo ọmọ ẹgbẹ okunkun l'Ọta


Ko din ni ogbologbo afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹta ti ọwọ palaba wọn segi niluu Sango Ọta, ipinlẹ Ogun laipẹ yii, ti wọn si ti wa nibi ti wọn ti n ka boroboro, paapaa lori iṣẹ buruku ti wọn ti ṣe sẹyin.

Dakwo Micheal Jackson, Joel Obieva, ati Oluwaseun Bamidele lorukọ awọn mẹtẹẹta naa ti ọwọ palaba wọn segi ninu ọgba ile-ẹkọ School 3 to wa ldugbo Jọju, Sango Ọta.
 
Awọn kan la gbọ pe wọn ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo wi pe awọn afurasi ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun korajọ sinu ọgba ile-ẹkọ naa lati da wahala silẹ, idi ree ti wọn l'awọn ọlọpaa fi tẹkọ leti lati lọ koju wọn.

Wọn ni ibi ipade naa ti wọn ti n pinnu lori ọna ti wọn yoo gba lati fi da wahala silẹ, paapaa lati koju awọn alatako wọn ni awọn ọlọpaa ti yọ si wọn lojiji, tọwọ si tẹ mẹta ninu wọn, ko to di pe awọn yooku juba ehoro.
 
Bọwọ ṣe tẹ awọn mẹta yii ni wọn ti bẹrẹ sii ka boroboro wi pe inu ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ lawọn wa, ati pe marun-un ni wọn. Wọn jẹwọ pe awọn fipade sile-ẹkọ naa ni lati pinnu ọna ti wọn yoo gba lọ ṣiṣẹ buruku wọn, ko to di pe ọlọjọ de.
 
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla nigba to n sọrọ ninu atẹjade to fi sita sọ pe iwadii ti bẹrẹ lati rọwọ to awọn yooku to na papa bora, to si loun nigbagbọ wi pe ọwọ yoo tẹ wọn laipẹ, ṣugbọn sibẹ, o ni lẹyin iwadii, awọn tọwọ tẹ yii yoo foju ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI