Tiransifọma ilu ni Adewọle at'awọn ọrẹ rẹ fẹẹ jigbe k'ọwọ too tẹ ẹ l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, September 8, 2023

Tiransifọma ilu ni Adewọle at'awọn ọrẹ rẹ fẹẹ jigbe k'ọwọ too tẹ ẹ l'Ogun


Ọrọ ti Jesu Oluwa sọ gbẹyin lori igi agbelebu l'ọjọ wi pe 'O pari', naa lo jabọ lẹnu ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Adewọle Adekunle, ẹni tọwọ nibi toun pẹlu awọn ọrẹ rẹ ti lọ ji ẹrọ amunawa tiransifọma gbe lagbegbe Showọ niluu Kọbapẹ to wa lopopona marosẹ Ṣagamu si Abẹokuta, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi-Owode, ipinlẹ Ogun.

Bakan naa, ka ni ki i ṣe pe awọn ara agbegbe naa ko sun asunpara ni, o ṣee ṣe ki wọn ri ẹrọ amunawa naa jigbe salọ, ki ẹnikẹni ma si mọ bo ṣe poora.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe nnkan bi aago mẹrin aabọ aarọ kutu ọjọ Ẹti tii ṣe Furaide to kọja yii ni wọn sọ pe Adewọle at'awọn ọrẹ rẹ lọ ji ẹrọ amunawa ijọba naa gbe, ṣugbọn ti awọn kan kofiri wọn.
 
Bi wọn ṣe kofiri wọn la gbọ pe wọn ti ta ileeṣẹ ọlọpaa ẹkun Owode Ẹgba lolobo, ti wọn si l'awon ọlọpaa yii ko f'ọrọ naa falẹ rara ki wọn to lọ ba wọn.
 
A gbọ pe bi wọn ṣe kofiri pe awọn ọlọpaa ti n bọ lọdọ wọn, ni wọn ti juba ehoro, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ Adewọle, ọkan lara wọn, ẹni ti wọn lo n gbe lojule kejidinlọgbọn, adugbo Ẹlẹkọ, Ajah n'ipinlẹ Ekoo.
 
Gbogbo igbiyanju lati rọwọ to awọn yooku lo ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, gẹgẹ bi agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla ṣe sọ.
 
Odutọla ni mọto nla Volkswagen ti nọmba idanimọ rẹ jẹ EKY 202 YG, eyi ti wọn gbe wa ni awọn ti gba silẹ, bẹẹ l'awọn tun gba foonu Itel pẹlu awọn irinṣẹ ti wọn fi tu ẹrọ amunawa naa bii digger, chisel, spanners, small bolts marundinlọgbọn, pincher ati bẹẹ lọ.
 
Siwaju si i ni Odutọla sọ pe awọn ti ri iwe mọto ti wọn gbe wa naa, eyi t'awọn yoo fi tọpinpin ẹni to nii ati awọn yooku to na papa bora, ati pe Adewọle funra rẹ naa ti n jẹwọ bi wọn ṣe le ri wọn mu.
 
Bakan naa lo sọ pe awọn ti fi to ọga awọn, Abiọdun Alamutu leti, to si ti paṣẹ pe ki wọn gbe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ lọ sile ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI