AFCON 2023: Bayii ni awọn agbabọọlu Afrika yoo ṣe koju ara wọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, October 13, 2023

AFCON 2023: Bayii ni awọn agbabọọlu Afrika yoo ṣe koju ara wọn


Ajọ to n ṣakoso ere idaraya nilẹ Afrika ti ṣagbekalẹ bi awọn ẹgbẹ agbabọọlu l'awọn orileede kọọkan to peregede fun dije ife ẹyẹ ilẹ adulawọ to fẹẹ waye lorileede Ivory Coast yoo ṣe koju ara wọn.


Isọri akọkọ ti a mọ si 'A' ni ikọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles lati orileede Naijiria wa, ti wọn yoo si maa wa a ko pẹlu Ivory Coast to fẹẹ gbalejo awọn orileede kaakiri Afrika.

Papa Iṣere Parc des Expositions to wa niluu Abidjan ni wọn ti pin awọn ẹgbẹ agbabọọlu si isọri-isọri.

Ẹgbẹ agbabọọlu Sẹnẹgal ti wọn wa ni ipo akọkọ nilẹ Afrika ni wọn ti pin si isọri kẹta ti a mọ si 'C', nibẹ sii ni wọn yoo ti maa koju awọn akẹgbẹ wọn lati Cameroon, Guinea ati Gambia.

Inu oṣu kin-ni-in, ọdun 2024 ni idije ọhun yoo bẹrẹ.

Wọnyi ni bi awọn egbẹ agbaboọlu yoo ṣe koju ara wọn:

Isọri A
Ivory Coast
Nigeria
Equatorial Guinea
Guinea-Bissau

Isọri B
Egypt
Ghana
Cape Verde
Mozambique

Isọri D
Senegal
Cameroon
Guinea
Gambia

Isọri E
Algeria
Burkina Faso
Mauritania
Angola

Isọri Ẹ
Tunisia
Mali
South Africa
Namibia

Isọri F
Morocco
DR Congo
Zambia
Tanzania.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI